Ìwé Orin Solomoni
11Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.
Olólùfẹ́
2Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
3Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.
Ọ̀rẹ́
Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.
Olólùfẹ́
Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
5Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
6Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
7Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
Ọ̀rẹ́
8Bí ìwọ kò bá mọ̀,
ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
Olùfẹ́
9Olùfẹ́ mi,
mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.
10Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,
ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.
11A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,
a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
Olólùfẹ́
12Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,
òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,
òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.
14Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi
láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.
Olùfẹ́
15Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!
Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
Olólùfẹ́
16Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe wu ni!
Ibùsùn wa ní ìtura.
Olùfẹ́
17Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari
ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.
2Olólùfẹ́
1Èmi ni ìtànná Ṣaroni
bí ìtànná lílì àwọn àfonífojì.
Olùfẹ́
2Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún
ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.
Olólùfẹ́
3Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,
ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin.
Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,
èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
4Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,
ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
5Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.
Fi èso ápù tù mi lára
nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi
ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra.
7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú
kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
8Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!
Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín.
Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.
10Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn.
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi,
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
Olùfẹ́
14Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,
ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,
fi ojú rẹ hàn mí,
jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;
nítorí tí ohùn rẹ dùn,
tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,
àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké
tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,
àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.
Olólùfẹ́
16Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;
Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.
17Títí ìgbà ìtura ọjọ́
títí òjìji yóò fi fò lọ,
yípadà, olùfẹ́ mi,
kí o sì dàbí abo egbin
tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
lórí òkè Beteri.
31Ní orí ibùsùn mi ní òru
mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;
mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,
ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;
èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀
ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ
títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,
sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.
5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá
bí ọ̀wọ̀n èéfín
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára
pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,
àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,
àwọn akọni Israẹli,
8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,
gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,
idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,
wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru
9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;
o fi igi Lebanoni ṣe é.
10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,
o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.
Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,
inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.
“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,
kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,
adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e
ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,
ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.
4Olùfẹ́
1Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!
Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!
Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ
irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.
Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.
2Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò
tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;
olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;
kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
3Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;
ẹnu rẹ̀ dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate
lábẹ́ ìbòjú rẹ.
4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,
tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;
lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́,
gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
5Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì
tí wọ́n jẹ́ ìbejì
tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.
6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀
tí òjìji yóò fi fò lọ,
èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá
àti sí òkè kékeré tùràrí.
7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;
kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.
8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,
ki a lọ kúrò ní Lebanoni.
Àwa wò láti orí òkè Amana,
láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,
láti ibi ihò àwọn kìnnìún,
láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.
9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìwọ ti gba ọkàn mi
pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,
pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.
10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!
Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,
òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!
11Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;
wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.
Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.
12Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.
13Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni
ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,
14nadi àti Safironi,
kalamusi àti kinamoni,
àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,
òjìá àti aloe
pẹ̀lú irú wọn.
15Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè,
ìṣàn omi láti Lebanoni wá.
Olólùfẹ́
16Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá
kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù!
Fẹ́ lórí ọgbà mi,
kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.
Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀
kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.
5Olùfẹ́
1Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.
Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;
mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.
Ọ̀rẹ́
Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,
àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.
Olólùfẹ́
2Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.
Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,
orí mi kún fún omi ìrì,
irun mi kún fún òtútù òru.”
3Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?
Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi
ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn
inú mi sì yọ́ sí i.
5Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,
òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn
sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.
6Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ
ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.
Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.
Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.
7Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.
Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;
wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín
bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,
kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?
Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
Ọ̀rẹ́
9Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ
tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?
Olólùfẹ́
10Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n
ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.
11Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ
ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ
ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.
12Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà
ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,
tí a fi wàrà wẹ̀,
tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.
13Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí
tí ó sun òórùn tùràrí dídùn
Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì
ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.
14Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká.
Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán
tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
15Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabu
tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára.
Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,
tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.
16Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀
ó wu ni pátápátá.
Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.
6Ọ̀rẹ́
1Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a?
Olólùfẹ́
2Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ.
3Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
Olùfẹ́
4Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,
ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,
ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5Yí ojú rẹ kúrò lára mi;
nítorí ojú rẹ borí mi.
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́
tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
6Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,
tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,
gbogbo wọn bí ìbejì,
kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,
rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.
8Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,
àti ọgọ́rin àlè,
àti àwọn wúńdíá láìníye.
9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,
ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,
ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún
àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.
Ọ̀rẹ́
10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,
tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,
tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
Olùfẹ́
11Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi
láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,
láti rí i bí àjàrà rúwé,
tàbí bí pomegiranate ti rudi.
12Kí èmi tó mọ̀,
àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
Ọ̀rẹ́
13Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati;
padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.
Olùfẹ́
Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,
bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?
71Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà.
Ìwọ ọmọbìnrin ọba!
Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́
iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2Ìdodo rẹ rí bí àwo
tí kì í ṣe aláìní ọtí,
ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama
tí a fi lílì yíká.
3Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì
tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.
Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni
ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.
Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni
tí ó kọ ojú sí Damasku.
5Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká,
bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká
a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó
báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
7Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,
àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
8Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ,
èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.”
Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,
àti èémí imú rẹ bí i ápù.
9Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.
Olólùfẹ́
Tí ó kúnná tí ó sì dùn,
tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
10Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,
èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
11Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,
jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.
12Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù
láti wo bí àjàrà rúwé
bí ìtànná àjàrà bá là.
Àti bí pomegiranate bá ti rudi,
níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde
ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,
èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́
tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
81Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi,
èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!
Èmi ìbá rí ọ ní òde,
èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,
wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
2Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́
èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi,
ìwọ ìbá kọ́ mi.
Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu,
àti oje èso pomegiranate mi.
3Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
4Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà.
Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè.
Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.
Ọ̀rẹ́
5Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù,
tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀.
Olólùfẹ́
Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ
níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
6Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì
bí èdìdì lé apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,
ìjowú sì le bí isà òkú
jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
7Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
Ọ̀rẹ́
8Àwa ní arábìnrin kékeré kan,
òun kò sì ní ọmú,
kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,
ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
9Bí òun bá jẹ́ ògiri,
àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.
Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn,
àwa yóò fi pákó kedari dí i.
Olólùfẹ́
10Èmi jẹ́ ògiri,
ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́
bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀
bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.
11Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni
ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú
olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá
ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.
12Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;
ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni,
igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.
Olùfẹ́
13Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,
jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!
Olólùfẹ́
14Yára wá, Olùfẹ́ mi,
kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,
tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,
lórí òkè òórùn dídùn.