Ìwé Saamu

1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

Saamu 1

11.1-3: Jr 17.7-8.Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,

tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,

ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

2Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa

àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

3Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,

tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀

tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.

Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

4Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!

Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà

tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

5Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

6Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,

ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

2

Saamu 2

12.1-2: Ap 4.25-26.Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,

àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

2Àwọn ọba ayé péjọpọ̀

àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀

Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

3Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,

kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

4Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;

Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀

yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

6“Èmi ti fi ọba mi sí ipò

lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

72.7: Mt 3.17; Ap 13.33; Hb 1.5; 5.5; 2Pt 1.17.Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:

Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;

lónìí, èmi ti di baba rẹ.

82.8-9: If 2.26; 12.5; 19.15.Béèrè lọ́wọ́ mi,

Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,

òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.

9Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn

ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;

ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

11Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù

ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

12Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,

kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,

nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.

Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

3

Saamu 3

Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.

1Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!

Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!

2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé

“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

3Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

4Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

5Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

6Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn

tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

7Dìde, Olúwa!

Gbà mí, Ọlọ́run mi!

Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;

kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

8Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.

Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

4

Saamu 4

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.

1Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,

ìwọ Ọlọ́run òdodo mi.

Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;

ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

2Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?

Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

3Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;

Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

44.4: Ef 4.26.Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀,

nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,

ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

5Ẹ rú ẹbọ òdodo

kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”

Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

7Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi

ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

8Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,

nítorí ìwọ nìkan, Olúwa,

ni o mú mi gbé láìléwu.

5

Saamu 5

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.

1Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,

kíyèsi àròyé mi.

2Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,

ọba mi àti Ọlọ́run mi,

nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

3Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;

ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀

èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

4Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;

bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

5Àwọn agbéraga kò le è dúró

níwájú rẹ̀.

Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;

6ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.

Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn

ni Olúwa yóò kórìíra.

7Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,

èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;

ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba

sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

8Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,

nítorí àwọn ọ̀tá mi,

mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.

95.9: Ro 3.13.Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;

ọkàn wọn kún fún ìparun.

Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;

pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

10Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!

Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.

Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;

jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.

Tan ààbò rẹ sórí wọn,

àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

12Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;

ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.

6

Saamu 6

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ

kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.

2Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;

Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.

3Ọkàn mi wà nínú ìrora.

Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?

4Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;

gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.

5Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.

Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?

6Agara ìkérora mi dá mi tán.

Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,

mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.

7Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;

wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.

86.8: Mt 7.23; Lk 13.27.Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,

nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.

9Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;

Olúwa ti gba àdúrà mi.

10Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;

wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

7

Saamu 7

Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.

1Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;

gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,

2kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,

wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.

3Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí

tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi.

4bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,

tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí,

5nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;

jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀

kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.

6Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;

dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.

Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.

7Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.

Jọba lórí wọn láti òkè wá.

8Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.

Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,

gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.

97.9: If 2.23.Ọlọ́run Olódodo,

Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,

tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú

tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

10Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,

ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.

11Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,

Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.

12Bí kò bá yípadà,

Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;

ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.

13Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;

ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.

14Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,

tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.

15Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde

jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.

16Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;

ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.

17Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,

èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.

8

Saamu 8

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, Olúwa wa,

orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga

ju àwọn ọ̀run lọ.

28.2: Mt 21.16.Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú

ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,

láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

3Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,

iṣẹ́ ìka rẹ,

òṣùpá àti ìràwọ̀,

tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,

4kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,

àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

5Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,

ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.

6Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;

ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:

7àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,

àti ẹranko igbó,

8ẹyẹ ojú ọrun,

àti ẹja inú Òkun,

àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.

9Olúwa, Olúwa wa,

orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

9

Saamu 9

Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

1Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.

2Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;

èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;

wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.

4Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;

ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.

5Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;

Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.

6Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,

ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;

àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.

7Olúwa jẹ ọba títí láé;

ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.

89.8: Ap 17.31.Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;

yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.

9Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,

ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.

10Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,

nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

11Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;

kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.

12Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;

òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!

Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,

14kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ

ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni

àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

15Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;

ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.

16A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;

àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

17Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,

àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

18Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,

ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

19Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;

jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.

20Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;

jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.

10

Saamu 10

1Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?

Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

2Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,

ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.

3Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;

Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.

4Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;

kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.

5Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;

òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;

òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.

6O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí.

Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

710.7: Ro 3.14.Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;

wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

8Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò.

Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.

Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.

9Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;

Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;

ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.

10Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;

kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.

11Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;

Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”

12Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.

Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

13Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?

Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,

“Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?

14Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;

Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.

Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

15Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;

pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀

tí a kò le è rí.

16Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;

àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.

17Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;

Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,

18láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,

kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,

kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

11

Saamu 11

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

1Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.

Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,

“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

2Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;

wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn

láti tafà níbi òjìji

sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.

3Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́

kí ni olódodo yóò ṣe?”

4Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;

Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.

Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;

ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

5Olúwa ń yẹ olódodo wò,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá

ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

6Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò

ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;

àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

7Nítorí, olódodo ní Olúwa,

o fẹ́ràn òdodo;

ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

12

Saamu 12

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

1Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;

olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.

2Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;

ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

3Olúwa kí ó gé ètè èké wọn

àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

4tí ó wí pé,

“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;

àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

5“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,

Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí.

“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”

6Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,

gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,

tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

7Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́

kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.

8Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri

nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.

13

Saamu 13

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?

Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

2Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,

àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?

Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?

3Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.

Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.

4Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”

àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

5Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;

ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

6Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,

nítorí ó dára sí mi.

14

Saamu 14

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

114.1-3: Ro 3.10-12.14.1-7: Sm 53.1-6.Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,

“Ko sí Ọlọ́run.”

Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;

kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

2Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá

lórí àwọn ọmọ ènìyàn

bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,

ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

3Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;

kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,

kò sí ẹnìkan.

4Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;

wọn kò sì ké pe Olúwa?

5Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,

nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,

ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

7Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!

Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,

jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

15

Saamu 15

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?

Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

2Ẹni tí ń rìn déédé

tí ó sì ń sọ òtítọ́,

láti inú ọkàn rẹ̀;

3tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,

tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀

tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,

4ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn

ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,

ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀

àní tí kò sì yípadà,

5tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé

tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí

ni a kì yóò mì láéláé.

16

Saamu 16

Miktamu ti Dafidi.

1Pa mí mọ́, Ọlọ́run,

nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

2Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi,

lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”

3Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,

àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

4Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.

Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

5Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,

ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

6Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;

nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

7Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;

ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

816.8-11: Ap 2.25-28,31.Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

9Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

1016.10: Ap 13.35.nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

11Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;

Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,

pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

17

Saamu 17

Àdúrà ti Dafidi.

1Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;

fi etí sí igbe mi.

Tẹ́tí sí àdúrà mi

tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.

2Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;

kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

3Ìwọ ti dán àyà mi wò,

ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,

ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,

ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.

4Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,

èmi ti pa ara mi mọ́

kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.

5Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;

ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

6Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn

dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

7Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn

ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là

lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.

8Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;

fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,

9lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,

kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,

wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

11Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,

pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.

12Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,

àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;

gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.

14Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,

kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.

Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;

àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,

wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;

nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

18

Saamu 18

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé.

118.1-50: 2Sa 22.2-51.Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

2Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;

Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.

Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

3Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,

a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.

4Ìrora ikú yí mi kà,

àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

5Okùn isà òkú yí mi ká,

ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

6Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;

mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.

Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;

ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.

7Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,

ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;

wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

8Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;

iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,

ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.

9Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;

àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

10Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;

ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

11Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká

kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.

12Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ

pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná

13Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;

Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.

14Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,

ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.

15A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn,

a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé

nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,

nípa fífún èémí ihò imú rẹ.

16Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;

Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.

17Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,

láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.

18Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;

ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.

19Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;

Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.

20Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;

gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.

21Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;

èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

22Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;

èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.

23Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;

mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

24Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;

gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.

25Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,

sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,

26sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,

ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.

27O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,

ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.

28Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi

kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.

29Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;

pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.

30Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,

a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa

òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.

31Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?

Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?

32Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè

ó sì mú ọ̀nà mi pé.

33Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;

ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.

34Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;

apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.

35Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,

ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;

àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.

36Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,

kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.

37Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn

èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.

38Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;

wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;

ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi

èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,

àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.

42Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;

mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.

43Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;

Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.

Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,

44ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;

àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.

45Àyà yóò pá àlejò;

wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.

46Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!

Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

47Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,

tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,

48tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.

Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;

lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.

4918.49: Ro 15.9.Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa;

èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

50Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;

ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀,

fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.

19

Saamu 19

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;

àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

2Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;

wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

3Kò sí ohùn tàbí èdè

níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn.

419.4: Ro 10.18.Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,

ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.

Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,

òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.

6Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá

àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;

kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

7Pípé ni òfin Olúwa,

ó ń yí ọkàn padà.

Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,

ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8Ìlànà Olúwa tọ̀nà,

ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.

Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,

ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

9Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,

ó ń faradà títí láéláé.

Ìdájọ́ Olúwa dájú

òdodo ni gbogbo wọn.

10Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,

ju wúrà tí o dára jùlọ,

wọ́n dùn ju oyin lọ,

àti ju afárá oyin lọ.

11Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;

nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

12Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?

Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

13Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;

má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.

Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,

èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi

kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,

Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

20

Saamu 20

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;

kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

2Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́

kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ

kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.

4Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ

kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.

5Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun

àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.

Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

6Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé,

Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́.

Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá

pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

7Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,

ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

8Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,

ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

9Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!

Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

21

Saamu 21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,

àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

2Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,

bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.

3Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà

ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

4Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,

àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

5Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;

ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.

6Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:

ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.

7Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;

nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà

kì yóò sípò padà.

8Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.

9Nígbà tí ìwọ bá yọ

ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.

Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,

àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.

10Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,

àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.

11Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ

wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.

12Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà

nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;

a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

22

Saamu 22

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

122.1: Mt 27.46; Mk 15.34.Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?

Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,

àní sí igbe ìkérora mi?

2Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:

àti ní òru èmi kò dákẹ́.

3Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;

ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

4Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;

wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

5Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;

ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

6Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;

mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.

7Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;

wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

8“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;

jẹ́ kí Olúwa gbà á là.

Jẹ́ kí ó gbà á là,

nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

9Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;

ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.

10Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,

nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11Má ṣe jìnnà sí mi,

nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí

kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;

àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.

13Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,

tí ń ké ramúramù.

14A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,

gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.

Ọkàn mi sì dàbí i ìda;

tí ó yọ́ láàrín inú mi.

15Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,

ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;

ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16Àwọn ajá yí mi ká;

ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,

wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.

17Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;

àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.

18Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn

àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi.

Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!

20Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,

àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

21Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;

kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;

nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.

23Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!

Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!

Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!

24Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra

ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;

kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi

ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;

ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀

26tálákà yóò jẹ yóò sì yó;

àwọn tí n wá Olúwa yóò yin

jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí

wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,

àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè

ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,

28nítorí ìjọba ni ti Olúwa.

Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;

gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀

àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.

30Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;

a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa.

31Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀

sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,

wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

23

Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

223.2: If 7.17.Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,

Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

3Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.

Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo

nítorí orúkọ rẹ̀.

4Bí mo tilẹ̀ ń rìn

láàrín àfonífojì òjìji ikú,

èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

wọ́n ń tù mí nínú.

5Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi

ní ojú àwọn ọ̀tá à mi.

Ìwọ ta òróró sí mi ní orí;

ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.

6Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn

ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,

èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa

títí láéláé.

24

Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

124.1: 1Kọ 10.26.Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,

ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

2nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun

ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?

Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

424.4: Mt 5.8.Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,

ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán

tí kò sì búra èké.

5Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,

àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

6Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,

tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

7Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;

kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!

Kí ọba ògo le è wọlé.

8Ta ni ọba ògo náà?

Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,

Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

9Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;

kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,

kí Ọba ògo le è wọlé wá.

10Ta ni Ọba ògo náà?

Olúwa àwọn ọmọ-ogun

Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

25

Saamu 25

Ti Dafidi.

1Olúwa,

ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.

2Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;

má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí

má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.

3Ẹni tí ó dúró tì ọ́

ojú kì yóò tì í,

àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí

ni kí ojú kí ó tì.

4Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,

kọ mi ní ipa tìrẹ;

5ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,

nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;

ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.

6Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,

torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.

7Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi

tàbí ìrékọjá mi;

gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi

nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

8Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:

nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.

9Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,

ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.

10Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,

fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.

11Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,

dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.

12Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?

Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

13Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,

àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

14Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;

ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.

15Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,

nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

16Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;

nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.

17Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;

kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.

18Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,

kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.

19Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,

tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

20Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;

má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,

nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

21Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;

nítorí pé mo dúró tì ọ́.

22Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,

nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!

26

Saamu 26

Ti Dafidi.

1Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,

nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,

mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa,

ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

2Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,

dán àyà àti ọkàn mi wò;

3nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,

èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

4Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

5Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú

èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

6Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.

7Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,

èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

8Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,

àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

9Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

10àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;

rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;

nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

27

Saamu 27

Ti Dafidi.

1Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;

ta ni èmi yóò bẹ̀rù?

Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,

ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

2Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi

láti jẹ ẹran-ara mi,

àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,

wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

3Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,

ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;

bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,

nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

4Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,

òhun ni èmi yóò máa wá kiri:

kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa

ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,

kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,

kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

5Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú

òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;

níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;

yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

6Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè

ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;

èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;

èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

7Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa,

ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,

8Ọkàn mi wí pé, “Wá ojú u rẹ̀!”

Ojú rẹ, Olúwa, ni ti èmí ń wá.

9Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,

má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;

ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,

Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,

háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,

Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

11Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú

nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,

nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,

wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,

èmi yóò rí ìre Olúwa

ní ilẹ̀ alààyè.

14Dúró de Olúwa;

kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le

àní dúró de Olúwa.

28

Saamu 28

Ti Dafidi.

1Ìwọ Olúwa,

mo ké pe àpáta mi.

Má ṣe kọ etí dídi sí mi.

Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,

èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,

bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,

bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè

sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.

3Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,

pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,

tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn

ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

4San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn

àti fún iṣẹ́ ibi wọn;

gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;

kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

5Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,

tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀

òun ó rún wọn wọlẹ̀

kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

6Alábùkún fún ni Olúwa!

Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7Olúwa ni agbára mi àti asà mi;

nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.

Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀

àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

8Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀

òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.

9Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;

di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

29

Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

1Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,

ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

2Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;

sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

3Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;

Ọlọ́run ògo sán àrá,

Olúwa san ara.

4Ohùn Olúwa ní agbára;

ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

5Ohùn Olúwa fa igi kedari;

Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.

6Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,

àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.

7Ohùn Olúwa ń ya

bí ọwọ́ iná mọ̀nà.

8Ohùn Olúwa ń mi aginjù.

Olúwa mi aginjù Kadeṣi.

9Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,

ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.

Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”

10Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;

Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.

11Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;

bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

30

Saamu 30

Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

1Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,

nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè

tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.

2Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,

ìwọ sì ti wò mí sàn.

3Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,

mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

4Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;

kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.

5Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,

ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;

ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,

ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

6Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,

“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”

7Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,

ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;

ìwọ pa ojú rẹ mọ́,

àyà sì fò mí.

8Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;

àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:

9“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,

nínú lílọ sí ihò mi?

Eruku yóò a yìn ọ́ bí?

Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?

10Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;

ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;

ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

12nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.

Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

31

Saamu 31

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;

má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;

gbà mí nínú òdodo rẹ.

2Tẹ́ etí rẹ sí mi,

gbà mí kíákíá;

jẹ́ àpáta ààbò mi,

jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.

3Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,

nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.

4Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,

nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

5Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;

ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

6Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;

ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

7Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,

nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi

ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.

8Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́

ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.

9Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;

ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,

ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

10Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi

àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;

agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,

egungun mi sì ti rún dànù.

11Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,

pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,

mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;

àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.

12Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;

èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.

1331.13: Jr 6.25; 20.3,10; 46.5; 49.29.Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;

tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,

wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi

láti gba ẹ̀mí mi.

14Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa;

mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;

gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi

àti àwọn onínúnibíni.

16Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;

gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

17Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;

nítorí pé mo ké pè ọ́;

jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;

jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.

18Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,

pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,

wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,

èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn

tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

20Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí

kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;

ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu

kúrò nínú ìjà ahọ́n.

21Olùbùkún ni Olúwa,

nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,

nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.

22Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,

“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”

Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú

nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!

Olúwa pa olódodo mọ́,

ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

24Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le

gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

32

Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

132.1-2: Ro 4.7-8.Ìbùkún ni fún àwọn

tí a dárí ìrékọjá wọn jì,

tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà

ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn

àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3Nígbà tí mo dákẹ́,

egungun mi di gbígbó dànù

nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru

ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;

agbára mi gbẹ tán

gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

5Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ

àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.

Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́

ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”

ìwọ sì dárí

ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

6Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ

ní ìgbà tí a lè rí ọ;

nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,

wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

7Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;

ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;

ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

8Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn

èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

9Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,

tí kò ní òye

ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,

kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.

10Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin

ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;

ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

33

Saamu 33

1Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo;

ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.

2Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;

ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

3Ẹ kọ orin tuntun sí i;

ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

4Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,

gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.

5Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;

ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

6Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,

àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.

7Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;

ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.

8Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:

jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.

9Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;

ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.

10Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;

ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.

11Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,

àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,

àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.

13Olúwa wò láti ọ̀run wá;

Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́

Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,

ó sì kíyèsi ìṣe wọn.

16A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;

kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.

17Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;

bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.

18Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.

19Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú

àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

20Ọkàn wa dúró de Olúwa;

òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.

21Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,

nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.

22Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,

àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

34

Saamu 34

Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.

1Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;

ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

2Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;

jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

3Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;

kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

4Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;

Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

5Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;

ojú kò sì tì wọ́n.

6Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;

ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

7Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká

ó sì gbà wọ́n.

8Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;

ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

9Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

10Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;

ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

11Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;

èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

1234.12-16: 1Pt 3.10-12.Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;

kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

13Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi

àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

14Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;

wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

15Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;

etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.

16Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;

láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,

Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

18Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;

ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

19Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,

ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

20Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;

kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,

àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.

22Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;

kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.

35

Saamu 35

Ti Dafidi.

1Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;

kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

2Di asà àti àpáta mú,

kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!

3Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ

kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.

Sọ fún ọkàn mi pé,

“Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

4Kí wọn kí ó dààmú,

kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;

kí a sì mú wọn padà,

kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.

5Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,

kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.

6Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,

kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

7Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,

ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.

8Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.

Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;

kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.

9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,

àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.

10Gbogbo egungun mi yóò wí pé,

“Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?

O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,

tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;

wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.

12Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;

láti sọ ọkàn mi di òfo.

13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;

mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.

Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;

14èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀

bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.

Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́

bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.

15Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;

wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.

Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.

16Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ

wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

17Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?

Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,

àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.

18Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;

èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

1935.19: Sm 69.4; Jh 15.25.Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi

kí ó yọ̀ lórí ì mi;

bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi

ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.

20Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,

ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn

sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.

21Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!

Ojú wa sì ti rí i.”

22Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!

Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!

23Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,

àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!

24Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,

kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!

25Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”

Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”

26Kí ojú kí ó tì wọ́n,

kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,

àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi

kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.

27Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi

fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;

kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa,

sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”

28Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,

àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

36

Saamu 36

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa.

136.1: Ro 3.18.Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú

jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé,

ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí

níwájú wọn.

2Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn

títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

3Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;

wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀.

4Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:

wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára

wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

5Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,

òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.

6Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,

àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;

ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

7Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!

Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.

8Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;

ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.

9Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:

nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

10Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n

àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!

11Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,

kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.

12Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:

a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!

37

Saamu 37

Ti Dafidi.

1Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,

kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

2nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,

wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.

3Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;

torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

4Ṣe inú dídùn sí Olúwa;

òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

5Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;

gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.

6Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

7Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,

kí o sì fi sùúrù dúró dè é;

má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,

nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.

8Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,

má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.

9Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,

ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

10Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;

nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.

11Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,

wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

12Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,

wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;

13ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,

nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.

14Ènìyàn búburú fa idà yọ,

wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,

láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,

láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.

15Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,

àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.

16Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,

sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;

17nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,

àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.

19Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,

àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.

Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;

wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,

ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;

22nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,

àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

23Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;

24bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,

nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.

25Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;

síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,

tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.

26Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;

a sì máa bùsi i fún ni.

27Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;

nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.

28Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,

kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,

ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.

29Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,

yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

31Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;

àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,

Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

33Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,

nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

34Dúró de Olúwa,

kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.

Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;

nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

35Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,

ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,

36ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;

bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.

37Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;

nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.

38Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;

ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.

39Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;

òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú

40Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;

yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,

nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

38

Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.

2Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,

ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.

3Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;

kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;

wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

5Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́

nítorí òmùgọ̀ mi.

6Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi

èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni

kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.

8Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;

mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;

ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;

bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.

11Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,

àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.

12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;

àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,

wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;

àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

14Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,

àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

15Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;

ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.

16Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;

nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,

ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

18Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;

àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

19Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.

20Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi

àwọn ni ọ̀tá mi

nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!

Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.

22Yára láti ràn mí lọ́wọ́,

Olúwa, Olùgbàlà mi.

39

Saamu 39

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

1Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi

kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;

èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu

níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”

2Mo fi ìdákẹ́ ya odi;

mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;

ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.

3Àyà mi gbóná ní inú mi.

Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;

nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:

4Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,

àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí

kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

5Ìwọ ti ṣe ayé mi

bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,

ọjọ́ orí mi sì dàbí asán

ní iwájú rẹ.

Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú

ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.

Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;

wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,

wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,

Olúwa,

kín ni mo ń dúró dè?

Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.

8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.

Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn

àwọn ènìyàn búburú.

9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;

èmi kò sì ya ẹnu mi,

nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

10Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;

èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.

11Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀

fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,

ìwọ a mú ẹwà rẹ parun

bí kòkòrò aṣọ;

nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12“Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,

kí o sì fetí sí igbe mi;

kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi.

Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ,

àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

13Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,

kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,

àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

40

Saamu 40

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

1Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;

ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2Ó fà mí yọ gòkè

láti inú ihò ìparun,

láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,

ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,

ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.

3Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,

àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.

Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,

wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

4Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì

tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn

tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,

tàbí àwọn tí ó yapa

lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5Olúwa Ọlọ́run mi,

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.

Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;

ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ,

tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,

wọ́n ju ohun tí

ènìyàn le è kà lọ.

640.6-8: Hb 10.5-9.Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,

ìwọ ti ṣí mi ní etí.

Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀

ni ìwọ kò béèrè.

7Nígbà náà ni mo wí pé,

“Èmi nìyí;

nínú ìwé kíká ni

a kọ ọ nípa tèmi wí pé.

8Mo ní inú dídùn

láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,

ìwọ Ọlọ́run mi,

òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

9Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà

láàrín àwùjọ ńlá;

wò ó,

èmi kò pa ètè mi mọ́,

gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,

ìwọ Olúwa.

10Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;

èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.

Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́

kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa;

jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ

kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.

12Nítorí pé àìníye ibi

ni ó yí mi káàkiri,

ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,

títí tí èmi kò fi ríran mọ́;

wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

àti wí pé àyà mí ti kùnà.

1340.13-17: Sm 70.1-5.Jẹ́ kí ó wù ọ́,

ìwọ Olúwa,

láti gbà mí là;

Olúwa,

yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì

kí wọn kí ó sì dààmú;

àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun

jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n,

àwọn tí ń wá ìpalára mi.

15Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”

ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.

16Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ

kí ó máa yọ̀

kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;

kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ

kí o máa wí nígbà gbogbo pé,

“Gbígbéga ni Olúwa!”

17Bí ó ṣe ti èmi ni,

tálákà àti aláìní ni èmi,

ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi

àti ìgbàlà mi;

má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,

ìwọ Ọlọ́run mi.

41

Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

1Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:

Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.

2Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:

yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀

kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

3Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀

yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

4Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;

wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

5Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,

“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

6Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,

wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;

nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

7Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;

èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

8wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin

àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,

kì yóò dìde mọ́.”

941.9: Jh 13.18.Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,

tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;

gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,

nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

12Bí ó ṣe tèmi ni

ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi

ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,

láé àti láéláé.

Àmín àti Àmín.

42

ÌWÉ KEJÌ

Saamu 42–72

Saamu 42

Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.

1Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.

2Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.

Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

3Oúnjẹ mi ni omijé mi

ní ọ̀sán àti ní òru,

nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,

“Ọlọ́run rẹ dà?”

4Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,

èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:

èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,

èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run

pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,

pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

5Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?

Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?

Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,

nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,

Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

6Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:

nítorí náà, èmi ó rántí rẹ

láti ilẹ̀ Jordani wá,

láti Hermoni láti òkè Mibsari.

7Ibú omi ń pe ibú omi

nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀

gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀

bò mí mọ́lẹ̀.

8Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,

àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi

àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

9Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,

“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?

Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,

nítorí ìnilára ọ̀tá?”

10Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí

àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,

bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.

“Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

11Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?

Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?

Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,

nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni

Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

43

Saamu 43

1Dá mi láre, Ọlọ́run mi,

kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:

yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.

2Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.

Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?

Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,

nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?

3Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,

jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;

jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,

sí ibi tí ìwọ ń gbé.

4Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,

sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,

èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,

ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

5Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?

Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?

Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,

nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni

Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

44

Saamu 44

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.

1À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run;

àwọn baba wa tí sọ fún wa

ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,

ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.

2Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde,

Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;

ìwọ run àwọn ènìyàn náà

Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.

3Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,

bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;

àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

4Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,

ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.

5Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;

nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,

6èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi,

idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

7ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,

ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

8Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,

àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá,

Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.

10Ìwọ ti bá wa jà,

ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,

àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,

wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

11Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn,

Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.

12Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,

Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,

ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

14Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;

àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

15Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,

ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

16nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn

ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

17Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,

síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ

bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.

18Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;

bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.

19Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,

ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,

tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa

tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

21Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,

níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?

2244.22: Ro 8.36.Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́

a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?

Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

24Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́

tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;

ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.

26Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;

rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

45

Saamu 45

Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.

1Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere

gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba

ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

2Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:

a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:

nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

3Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ

wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.

4Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́,

ìwà tútù àti òtítọ́;

jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.

5Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu

jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

645.6-7: Hb 1.8-9.Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,

ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.

7Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú

nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,

nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.

8Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;

láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe

orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.

9Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba

wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,

ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró

nínú wúrà Ofiri.

10Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi

gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.

11Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi

nítorí òun ni olúwa rẹ

kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.

12Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn

àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.

13Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,

iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.

14Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,

àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.

15Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn

wọ́n sì wọ ààfin ọba.

16Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀

ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

17Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,

nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.

46

Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.

1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa

ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,

tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì

tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,

ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:

Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,

ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

7Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,

Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa

irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.

9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé

ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì

ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.

10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.

A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

a ó gbé mi ga ní ayé.

11Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;

Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

47

Saamu 47

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn

ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.

2Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó

ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa

àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa

4Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,

ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.

5Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,

Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.

6Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.

Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!

7Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,

ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!

8Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;

Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.

9Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ

gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu

nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,

òun ni ó ga jùlọ.

48

Saamu 48

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

1Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn

ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

248.2: Mt 5.35.Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,

ayọ̀ gbogbo ayé,

òkè Sioni, ní ìhà àríwá

ní ìlú ọba ńlá.

3Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;

ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,

wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.

5Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n,

a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.

6Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,

ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.

7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,

wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

8Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,

bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,

ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun

ní ìlú Ọlọ́run wa,

Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

9Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,

àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.

10Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,

ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,

ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.

11Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀

kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn

nítorí ìdájọ́ rẹ.

12Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,

ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.

13Kíyèsi odi rẹ̀,

kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀

kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,

Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

49

Saamu 49

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!

Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.

2Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré

tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!

3Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,

èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

5Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?

Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,

6àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,

tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.

7Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀

padà tàbí san owó ìràpadà fún

Ọlọ́run.

8Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye

kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,

9ní ti kí ó máa wà títí ayé

láìrí isà òkú.

10Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,

bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé

wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,

ibùgbé wọn láti ìrandíran,

wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́

ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

13Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó

gbàgbọ́ nínú ara wọn,

àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,

tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.

14Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú

ikú yóò jẹun lórí wọn;

ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,

jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀.

Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,

isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

15Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà

kúrò nínú isà òkú,

yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.

16Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.

Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

17Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,

ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.

18Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.

Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.

19Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀

àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

50

Saamu 50

Saamu ti Asafu.

1Olúwa, Ọlọ́run alágbára,

sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ

láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.

2Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,

Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀

3Ọlọ́run ń bọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,

iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,

àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.

4Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,

kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.

5“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi

àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”

6Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,

nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́.

7“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:

èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.

8Èmi kí yóò bá ọ wí

nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,

tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi

ní ìgbà gbogbo.

9Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,

tàbí kí o mú òbúkọ láti

inú agbo ẹran rẹ̀

10nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi

àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún (1,000) òkè.

11Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá

àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.

12Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,

nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo

tí ó wa ní inú rẹ̀.

13Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí

mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14“Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,

kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.

15Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,

èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

16Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,

tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?

17Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,

ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.

18Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,

ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.

19Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,

ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.

20Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,

ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.

21Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;

ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,

ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,

èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22“Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.

23Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,

kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

51

Saamu 51

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.

1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,

gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀

kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.

2Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò

kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

3Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,

nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

451.4: Ro 3.4.Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí

ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,

kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,

kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.

5Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,

nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

6Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;

ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

7Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;

fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.

8Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;

jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.

9Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi

kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.

10Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,

kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,

kí o má ṣe gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.

12Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,

kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,

àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

14Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,

ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,

ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.

15Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,

àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.

16Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;

Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.

17Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

18Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,

ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.

19Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,

pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,

nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.

52

Saamu 52

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

1Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?

Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,

ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?

2Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;

ó dàbí abẹ mímú,

ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.

3Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,

àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.

4Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,

ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

5Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,

yóò sì dì ọ́ mú,

yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,

yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.

6Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù

wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,

7“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,

bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,

ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

8Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi

tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;

èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà

láé àti láéláé.

9Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;

èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,

nítorí orúkọ rẹ dára.

Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

53

Saamu 53

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.

153.1-3: Ro 3.10-12.53.1-6: Sm 14.1-7.Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé,

“Ọlọ́run kò sí.”

Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;

kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

2Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run

sórí àwọn ọmọ ènìyàn,

láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,

tí ó sì ń wá Ọlọ́run.

3Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,

wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;

kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

4Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?

Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun

tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?

5Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá

níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,

nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;

ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

6Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!

Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,

jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!

54

Saamu 54

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa?”

1Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:

dá mi láre nípa agbára rẹ.

2Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;

fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.

Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,

àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

4Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;

Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,

pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

5Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;

pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

6Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,

èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,

nítorí tí ó dára.

7Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo

ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

55

Saamu 55

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

1Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,

má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.

Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.

3Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,

nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;

nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,

wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;

ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;

ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!

Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,

kí ń sì dúró sí aginjù;

8èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,

jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

9Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,

nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

10Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;

ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.

11Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;

ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,

èmi yóò fi ara mọ́ ọn;

tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,

èmi ìbá sá pamọ́ fún un.

13Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,

ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,

14pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,

bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15Kí ikú kí ó dé bá wọn,

kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,

jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,

nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;

Olúwa yóò sì gbà mí.

17Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán

èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,

o sì gbọ́ ohùn mi.

18Ó rà mí padà láìléwu

kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,

nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní,

ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì Sela,

nítorí tí wọn kò ní àyípadà,

tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;

ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.

21Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,

ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;

ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,

ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

2255.22: 1Pt 5.7.Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa

yóò sì mú ọ dúró;

òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi

wá sí ihò ìparun;

àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,

kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

56

Saamu 56

Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.

1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,

nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;

ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.

2Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,

àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

3Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,

èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,

nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí

kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

5Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,

wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

6Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba.

Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi

wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

7San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;

ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.

8Kọ ẹkún mi sílẹ̀;

kó omijé mi sí ìgò rẹ,

wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?

9Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà

nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́

nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

10Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀

nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

11nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:

ẹ̀rù kì yóò bà mí.

Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

12Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:

èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.

13Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú

àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,

kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run

ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.

57

Saamu 57

Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,

nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.

Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ

títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

2Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,

sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.

3Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,

yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì

tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.

Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

4Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;

mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,

àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà

ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

5Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,

kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

6Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:

a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,

wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:

ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

757.7-11: Sm 108.1-5.Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;

ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.

8Jí, ìwọ ọkàn mi!

Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!

Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.

9Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;

èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.

10Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;

òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.

11Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;

kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

58

Saamu 58

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

1Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́

ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?

Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́

ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?

2Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,

ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

3Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,

lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.

4Oró wọn dàbí oró ejò,

wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,

5tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,

bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

6Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;

ní ẹnu wọn,

ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.

7Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;

nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.

8Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé

bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

9Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;

bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.

10Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,

nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.

11Àwọn ènìyàn yóò wí pé,

“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;

lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

59

Saamu 59

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

1Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;

dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.

2Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú

kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

3Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!

Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi

kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.

4Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.

Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.

5Olúwa Ọlọ́run Alágbára,

Ọlọ́run Israẹli,

dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;

má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.

6Wọ́n padà ní àṣálẹ́,

wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,

wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.

7Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:

wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,

wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

8Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín,

Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

9Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;

nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

10Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.

Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.

11Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,

kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.

Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,

kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,

ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,

kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.

Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,

13pa wọ́n run nínú ìbínú,

run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.

Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé

pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

14Wọ́n padà ní àṣálẹ́,

wọn ń gbó bí àwọn ajá

wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.

15Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ

wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.

16Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,

n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;

nítorí ìwọ ni ààbò mi,

ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;

ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.

60

Saamu 60

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀.

1Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,

Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,

ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.

2Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;

mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.

3Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;

ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.

4Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún

kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

560.5-12: Sm 108.6-13.Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,

kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.

6Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:

“Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde

èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.

7Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;

Efraimu ni àṣíborí mi,

Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

8Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;

lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

9Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?

Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?

10Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀

tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

11Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,

nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

12Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,

yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

61

Saamu 61

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

1Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;

tẹ́tí sí àdúrà mi.

2Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,

mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;

mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

3Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,

ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

4Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé

kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.

5Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;

Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

6Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,

ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.

7Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;

pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

8Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé

kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

62

Saamu 62

Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

1Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;

ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.

2Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;

Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

3Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?

Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,

bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

4Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú

kúrò nínú ọlá rẹ̀;

inú wọn dùn sí irọ́.

Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,

ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

5Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.

Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.

6Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;

Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.

7Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;

Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

8Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;

tú ọkàn rẹ jáde sí i,

nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

9Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn,

èké sì ni àwọn olóyè,

wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,

lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.

10Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,

tàbí gbéraga nínú olè jíjà,

nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,

má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

11Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì,

ni mo gbọ́ èyí pé,

“Ti Ọlọ́run ni agbára,

1262.12: Jr 17.10; If 2.23; 22.12.pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú;

nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”

63

Saamu 63

Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.

1Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,

nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,

òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,

ara mi fà sí ọ,

ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀

níbi tí kò sí omi.

2Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,

mo rí agbára àti ògo rẹ.

3Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,

ètè mi yóò fògo fún ọ.

4Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,

èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.

5A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;

pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.

6Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;

èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.

7Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,

mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

8Ọkàn mí fà sí ọ:

ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

9Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;

wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

10Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú

wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.

11Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run

ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo

ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.

64

Saamu 64

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi

pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

2Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú

kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

3Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,

wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.

4Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:

wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

5Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,

wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀

wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”

6Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,

“A wa ti parí èrò tí a gbà tán!”

Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;

wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.

8Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,

gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

9Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù

wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run

wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa

yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.

Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.

65

Saamu 65

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.

1Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;

sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,

gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.

3Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!

Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.

4Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn

tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!

A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,

ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

5Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,

Ọlọ́run olùgbàlà wa,

ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé

àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,

6ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,

tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,

7ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,

ríru ariwo omi wọn,

àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.

8Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,

nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;

ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,

ìwọ pè fún orin ayọ̀.

9Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;

ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.

Odò Ọlọ́run kún fún omi

láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,

nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.

10Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀

ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;

ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,

o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.

11Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,

ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.

12Pápá tútù ní aginjù ń kan

àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.

13Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;

àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,

wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

66

Saamu 66

Fún adarí orin. Orin. Saamu.

1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!

2Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;

ẹ kọrin ìyìnsí i.

3Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, “Ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!

Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ

ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́.

4Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;

wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,

wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.

5Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,

iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!

6Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,

wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,

níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.

7Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,

ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè

kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.

8Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,

jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;

9Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,

kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀.

10Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;

ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.

11Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n

o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.

12Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí

àwa la iná àti omi kọjá

ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

13Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,

kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ,

14ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ

nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.

15Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,

àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;

èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.

16Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;

ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.

17Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i,

ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.

18Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,

Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;

19ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́

ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.

20Ìyìn ni fún Ọlọ́run

ẹni tí kò kọ àdúrà mi

tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!

67

Saamu 67

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.

1Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,

kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,

2kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,

ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

3Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;

kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

4Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,

nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,

ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

5Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;

kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

6Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,

Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.

7Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,

àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

68

Saamu 68

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.

1Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;

kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.

2Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,

kí ó fẹ́ wọn lọ;

bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,

kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.

3Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn

kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;

kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

4Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,

ẹ kọrin ìyìn sí i,

ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.

Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

5Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé

rẹ̀ mímọ́

6Ọlọ́run gbé aláìlera

kalẹ̀ nínú ìdílé,

ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,

ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

7Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,

tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.

8Ilẹ̀ mì títí,

àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,

níwájú Ọlọ́run,

ẹni Sinai,

níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.

9Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;

ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.

10Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀

nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

11Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,

púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.

12“Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;

obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.

13Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,

nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,

àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”

14Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,

ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.

15Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;

òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.

16Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,

ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba

níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?

17Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run

ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;

Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.

18Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga

ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;

ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:

nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,

Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19Olùbùkún ni Olúwa,

Ọlọ́run Olùgbàlà wa,

ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.

20Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà

àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

21Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,

àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn

22Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;

èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,

23kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,

àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”

24Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,

ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.

25Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn;

àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.

26Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;

àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.

27Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,

níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,

níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.

28Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;

fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.

29Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu

àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.

30Bá àwọn ẹranko búburú wí,

tí ń gbé láàrín eèsún

ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù

pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù

títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:

tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.

31Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;

Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,

kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.

33Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,

tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

34Kéde agbára Ọlọ́run,

ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,

tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

35Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;

Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.

Olùbùkún ní Ọlọ́run!

69

Saamu 69

Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.

1Gbà mí, Ọlọ́run,

nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

2Mo ń rì nínú irà jíjìn,

níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.

Mo ti wá sínú omi jíjìn;

ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;

ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,

nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

469.4: Sm 35.19; Jh 15.25.Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí

wọ́n ju irun orí mi lọ,

púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,

àwọn tí ń wá láti pa mí run.

A fi ipá mú mi

láti san ohun tí èmi kò jí.

5Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;

ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

6Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,

Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;

má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,

Ọlọ́run Israẹli.

7Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,

ìtìjú sì bo ojú mi.

8Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;

àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

969.9: Jh 2.17; Ro 15.3.nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,

àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10Nígbà tí mo sọkún

tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà

èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,

àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.

12Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,

mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni

ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,

ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà

Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,

dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

14Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,

má ṣe jẹ́ kí n rì;

gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,

kúrò nínú ibú omi.

15Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì

kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.

16Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;

nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.

17Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:

yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;

rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

19Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;

gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.

20Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́,

wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́;

mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,

mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,

àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.

22Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn

ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ

fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,

kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.

2469.24: If 16.1.Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;

kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

2569.25: Ap 1.20.Kí ibùjókòó wọn di ahoro;

kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,

àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.

27Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;

Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.

2869.28: If 3.5; 13.8; 17.8; 20.12,15; 21.27.Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè

kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.

29Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,

Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

30Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga

èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

31Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ

ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

32Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:

ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

33Olúwa, gbọ́ ti aláìní,

kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,

òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,

35nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là

yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.

Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

36àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,

àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

70

Saamu 70

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

170.1-5: Sm 40.13-17.Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,

Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

2Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi

kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;

kí àwọn tó ń wá ìparun mi

yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.

3Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè

ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”

4Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀

kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,

kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,

“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

5Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;

wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;

Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

71

Saamu 71

1Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;

má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

2Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;

dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.

3Jẹ́ àpáta ààbò mi,

níbi tí èmi lè máa lọ,

pa àṣẹ láti gbà mí,

nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.

4Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,

ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

5Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,

ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.

6Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;

Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá

èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

7Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,

ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,

ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

9Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi,

má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.

10Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,

àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.

11Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;

lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,

nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

12Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;

wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.

13Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,

kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi

kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù

bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;

èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,

ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,

lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.

16Èmi ó wá láti wá kéde agbára,

Olúwa Olódùmarè;

èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.

17Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi

títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.

18Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,

má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,

títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,

àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,

ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá.

Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?

20Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,

ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí

ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè

láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.

Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

21Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi

ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22Èmi yóò fi dùùrù mi yìn

fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;

èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù

ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

23Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn

nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:

èmi, ẹni tí o rà padà.

24Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,

fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,

a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

72

Saamu 72

Ti Solomoni.

1Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,

ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún.

2Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,

yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.

3Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn

àti òkè kéékèèké nípa òdodo.

4Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn

yóò gba àwọn ọmọ aláìní;

yóò sì fa àwọn aninilára ya.

5Àwọn òtòṣì àti aláìní

yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,

níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,

yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.

6Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀,

bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.

7Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀

ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;

títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.

8Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun

àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.

9Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un

àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.

10Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù

wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;

àwọn ọba Ṣeba àti Seba

wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.

11Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un

àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.

12Nítorí yóò gba àwọn aláìní

nígbà tí ó bá ń ké,

tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

13Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní

yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.

14Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá

nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

15Yóò sì pẹ́ ní ayé!

A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.

Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo

kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.

16Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;

ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà

kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni

yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.

17Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;

orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.

Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.

Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

18Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,

ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.

19Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;

kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.

Àmín àti Àmín.

20Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.

73

ÌWÉ KẸTA

Saamu 73–89

Saamu 73

Saamu ti Asafu.

1Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,

fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

2Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;

ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.

3Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé

nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

4Wọn kò ṣe wàhálà;

ara wọn mókun wọn sì lágbára.

5Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;

a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.

6Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;

ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.

7Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;

ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.

8Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára,

wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.

9Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run

ahọ́n wọn gba ipò ayé.

10Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn

wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

11Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?

Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí,

ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;

nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.

14Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;

a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

15Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”

èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.

16Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,

Ó jẹ́ ìnilára fún mi,

17títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;

nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́

ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

19Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí

bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!

Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!

20Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,

bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,

ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21Nígbà tí inú mi bàjẹ́

àti ọkàn mi ṣì korò,

22mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;

mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;

ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi

ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

25Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?

Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.

26Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà

ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi

àti ìpín mi títí láé.

27Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé

ìwọ ti pa gbogbo wọn run;

tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

28Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run.

Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;

kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

74

Saamu 74

Maskili ti Asafu.

1Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?

Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?

2Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,

ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà.

Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.

3Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,

gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.

4Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù

láàrín ènìyàn rẹ,

wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.

5Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè

láti gé igi igbó dídí.

6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,

ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.

7Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀

wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.

8Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”

Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

9A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;

kò sí wòlíì kankan

ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.

10Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?

Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?

11Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?

Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!

12Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;

Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;

ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.

14Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù

tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;

ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.

15Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;

Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.

16Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;

ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.

17Ìwọ pààlà etí ayé;

Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa

bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.

19Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;

má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.

20Bojú wo májẹ̀mú rẹ,

nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.

21Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú

jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.

22Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;

rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

23Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,

bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.

75

Saamu 75

Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.

1A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,

a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;

àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

2Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;

Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.

3Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,

Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.

4Èmí wí fún àwọn agbéraga pé,

ẹ má ṣe gbéraga mọ́;

àti sí ènìyàn búburú;

ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.

5Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;

ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

6Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá

tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,

bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.

7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;

Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.

8Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,

ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,

ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,

àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

9Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;

èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.

10Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

76

Saamu 76

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.

1Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;

orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli

2Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,

ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.

3Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,

asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

4Ìwọ ni ògo àti ọlá,

ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.

5A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun

wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;

kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni

tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.

6Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,

àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

7Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.

Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?

8Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,

ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,

9nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,

bá dìde láti ṣe ìdájọ́,

láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.

10Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,

ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.

11Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;

kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká

mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.

12Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;

àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

77

Saamu 77

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.

1Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;

mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

2Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,

mo wá Olúwa;

ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀

ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.

3Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,

mo sì kẹ́dùn;

mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.

4Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,

mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;

ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6mo rántí orin mi ní òru.

Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,

ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.

7“Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?

Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?

8Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?

Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

9Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?

Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.

10Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,

pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.

11Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:

bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.

12Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo,

pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.

13Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.

Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

14Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;

ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.

15Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,

àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.

16Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,

nígbà tí àwọn omi rí ọ,

ẹ̀rù bà wọ́n,

nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.

17Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,

àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;

ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.

18Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,

ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;

ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

19Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,

ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,

nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.

20Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran

nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

78

Saamu 78

Maskili ti Asafu.

1Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;

tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

278.2: Mt 13.35.Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,

èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;

3ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,

ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.

4Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́

kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,

ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀

àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn

fún ìran tí ń bọ̀.

5Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu

o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,

èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa

láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

6nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí

tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.

7Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run

wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run

ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

8Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,

ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,

ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,

àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

9Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,

wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun

10Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́

wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.

11Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,

àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.

12Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.

13Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá

Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.

14Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn

àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.

15Ó sán àpáta ní aginjù

ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀

bí ẹni pé láti inú ibú wá.

16Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta

omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.

17Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i

ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.

18Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò

nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.

19Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé

“Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?

20Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,

odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀

ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ

ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”

21Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;

iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,

ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,

22nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,

wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.

23Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,

ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;

2478.24: Jh 6.31.Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,

ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.

25Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;

Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,

26Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá

ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.

27Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,

àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun

28Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,

yíká àgọ́ wọn.

29Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ

nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.

30Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,

nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,

31ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn

ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,

ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

32Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;

nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.

33O fi òpin sí ayé wọn nínú asán

àti ọdún wọn nínú ìpayà.

34Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,

wọn yóò wá a kiri;

wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

35Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;

wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn.

36Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n

wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;

3778.37: Ap 8.21.ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,

wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.

38Síbẹ̀ ó ṣàánú;

ó dárí àìṣedéédéé wọn jì

òun kò sì pa wọ́n run

nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà

kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè

39Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,

afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.

40Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù

wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!

41Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;

wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.

42Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:

ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,

43ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,

àti iṣẹ́ àmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani

44Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;

wọn kò lè mu láti odò wọn.

45Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,

àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.

46Ó fi ọkà wọn fún láńtata,

àwọn ìre oko wọn fún eṣú.

47Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́

ó bá èso sikamore wọn jẹ́.

48Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,

agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.

49Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,

ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,

nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.

50Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,

òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,

ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.

51Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti,

olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu.

52Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;

ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.

53Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n

ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

54Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀

òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà

55Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn

ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;

ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò

wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;

wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

57Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,

wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn

wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.

58Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;

wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.

59Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,

inú bí i gidigidi;

ó kọ Israẹli pátápátá.

60Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,

àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.

61Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,

dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

62Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,

ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.

63Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,

àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

64àfi àlùfáà wọn fún idà,

àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

65Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,

gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.

66Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;

ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.

67Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,

kò sì yan ẹ̀yà Efraimu,

68ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,

òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.

69Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,

gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.

70Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀

ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;

71Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn

láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu

àti Israẹli ogún un rẹ̀.

72Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;

pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.

79

Saamu 79

Saamu ti Asafu.

1Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;

wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,

wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.

2Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ

fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,

ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.

3Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi

yí Jerusalẹmu ká,

kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.

4Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,

àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.

5Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?

Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?

6Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè

tí kò ní ìmọ̀ rẹ,

lórí àwọn ìjọba

tí kò pe orúkọ rẹ;

7nítorí wọ́n ti run Jakọbu

wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.

8Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn

jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,

nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.

9Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,

fún ògo orúkọ rẹ;

gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì

nítorí orúkọ rẹ.

10Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,

“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”

Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.

11Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,

gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ

ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.

12San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje

nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.

13Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,

àti àgùntàn pápá rẹ,

yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;

láti ìran dé ìran

ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.

80

Saamu 80

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.

1Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;

ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran.

Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù,

tàn jáde 2níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.

Ru agbára rẹ̀ sókè;

wá fún ìgbàlà wa.

3Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;

jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí a bá à lè gbà wá là.

4Olúwa Ọlọ́run alágbára,

ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó

sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?

5Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn

ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

6Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,

àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

7Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;

jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,

kí a ba à lè gbà wá là.

8Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;

ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.

9Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,

ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀

ó sì kún ilẹ̀ náà.

10A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.

11O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,

ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.

12Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀

tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?

13Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́

àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

14Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!

Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!

Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

15gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,

àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.

16A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;

ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.

17Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.

18Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;

mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.

19Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;

kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí á ba à lè gbà wá là.

81

Saamu 81

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

1Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa

ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!

2Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,

tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

3Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun

àní nígbà tí a yàn;

ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.

4Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,

àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.

5Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu

nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

6Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,

a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.

7Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,

mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,

mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

8“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,

bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.

9Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;

ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.

10Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.

Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11“Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;

Israẹli kò ní tẹríba fún mi.

12Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn

láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13“Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi

bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,

14ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn

kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!

15Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.

Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.

16Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín

èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

82

Saamu 82

Saamu ti Asafu.

1Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,

ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

2“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo

kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?

3Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;

ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.

4Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;

gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

5“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,

wọn kò lóye ohun kankan.

Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;

à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

682.6: Jh 10.34.“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;

ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’

7Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;

ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

8Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,

nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

83

Saamu 83

Orin. Saamu ti Asafu.

1Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;

má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.

2Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,

bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

3Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;

wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.

4Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,

kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

5Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;

wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

6Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,

ti Moabu àti ti Hagari

7Gebali, Ammoni àti Amaleki,

Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.

8Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn

láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

9Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani

bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,

10ẹni tí ó ṣègbé ní Endori

tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,

àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,

12tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní

àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,

bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14Bí iná ti í jó igbó,

àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,

15bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn

dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.

16Fi ìtìjú kún ojú wọn,

kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé

kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn

18jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:

pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

84

Saamu 84

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,

Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

2Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́

ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa

àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀

sí Ọlọ́run alààyè.

3Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,

ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,

níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:

ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,

Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

4Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;

wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

5Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ

àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ

wọn sọ ọ́ di kànga

àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.

7Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá

títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

8Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;

tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.

9Wo asà wa, Ọlọ́run;

fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.

10Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ

ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ;

èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi

jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;

Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;

kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn

fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.

12Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

85

Saamu 85

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

1Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;

ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.

2Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì

ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.

3Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan

ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.

4Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,

kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.

5Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?

Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?

6Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,

pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?

7Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,

kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

8Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;

ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀,

ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.

9Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;

òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.

11Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá

òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.

12Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,

ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.

13Òdodo síwájú rẹ lọ

o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

86

Saamu 86

Àdúrà ti Dafidi.

1Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,

nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.

2Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:

ìwọ ni Ọlọ́run mi,

gbà ìránṣẹ́ rẹ là

tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

3Ṣàánú fún mi, Olúwa,

nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

4Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,

nítorí ìwọ, Olúwa,

ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.

5Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,

ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;

tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.

7Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,

nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.

8Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:

kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.

9Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá

yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;

wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.

10Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;

ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

11Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;

fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,

kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

13Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;

ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

14Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;

àti ìjọ àwọn alágbára ń wá

ọkàn mi kiri,

wọn kò sì fi ọ́ pè.

15Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,

Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.

16Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;

fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára

kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.

17Fi àmì hàn mí fún rere,

kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,

kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa

ni ó ti tù mí nínú.

87

Saamu 87

Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.

1Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

2Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni

ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

3Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,

ìlú Ọlọ́run,

4“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli

láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:

Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi,

yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

5Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,

“Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,

àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”

6Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:

“Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

7Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu

ohun èlò orin yóò wí pé,

“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

88

Saamu 88

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.

1Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,

ní ọ̀sán àti ní òru, mo kígbe sókè sí Ọ.

2Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;

dẹ etí rẹ sí igbe mi.

3Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú

ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.

4A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀

èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.

5A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú

bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,

ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,

ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

6Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,

ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.

7Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;

ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.

8Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi

ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.

A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;

9ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.

Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;

mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.

10Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?

Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?

11A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí,

tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?

12A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí

àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

13Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;

ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.

14Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí

tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

15Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,

èmi múra àti kú;

nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,

èmi di gbére-gbère.

16Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;

ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.

17Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;

wọ́n mù mí pátápátá.

18Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;

òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

89

Saamu 89

Maskili ti Etani ará Esra.

1Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;

pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

2Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,

pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.

389.3-4: Sm 132.11; Ap 2.30.Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi

mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.

4‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé

èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

5Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,

òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

6Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?

Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?

7Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;

ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

8Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ

ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

9Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;

nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.

10Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ

bí ẹni tí a pa;

ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ

tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:

ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:

ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

12Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;

Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.

13Ìwọ ní apá agbára;

agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

14Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:

ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.

15Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,

Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

16Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,

wọn ń yin òdodo rẹ.

17Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;

nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.

18Nítorí ti Olúwa ni asà wa,

ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

19Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé,

“Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,

èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.

2089.20: Ap 13.22.Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;

pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.

21Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀

apá mí yóò sì fi agbára fún un.

22Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,

àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.

23Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ

èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.

24Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ

àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.

25Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun,

àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.

26Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’

2789.27: If 1.5.Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,

ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.

28Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,

àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.

29Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,

àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

30“Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀

tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.

31Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́

tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,

32nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;

àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;

33ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.

34Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.

35Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;

èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.

36Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,

àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.

3789.37: If 1.5; 3.14.A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,

àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” Sela.

38Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;

ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.

39Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;

ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.

40Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀

ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.

41Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;

ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.

42Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;

ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.

43Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,

ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.

44Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,

ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

45Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;

ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.

46Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?

Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?

Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?

47Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó

nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!

48Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?

Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?

49Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,

tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?

50Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;

bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,

51ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa,

tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.

52Olùbùkún ní Olúwa títí láé.

Àmín àti Àmín.

90

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Saamu 90

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run.

1Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.

2Kí a tó bí àwọn òkè ńlá

àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,

láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

3Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,

wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”

490.4: 2Pt 3.8.Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá kọjá lójú rẹ,

bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.

5Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;

wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.

6Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun

ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

7A pa wá run nípa ìbínú rẹ

nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.

8Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,

àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.

9Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;

àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.

10Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,

bi ó sì ṣe pé nípa agbára

tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,

agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,

nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,

àwa a sì fò lọ.

11Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.

12Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,

kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?

Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.

14Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,

kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀

kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.

15Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,

fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.

16Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,

ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;

fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa,

bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

91

Saamu 91

1Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

2Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

“Òun ni ààbò àti odi mi,

Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

3Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

4Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

5Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

6tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

7Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

8Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ

àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,

ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

10Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,

Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.

1191.11-12: Mt 4.6; Lk 4.10-11.Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ

láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;

12wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,

nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.

1391.13: Lk 10.19.Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;

ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14“Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;

èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

15Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;

èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,

èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.

16Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,

èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

92

Saamu 92

Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi.

1Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa

àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,

2láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀

àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,

3lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá

àti lára ohun èlò orin haapu.

4Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn

nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;

èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

5Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?

Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!

6Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,

aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,

7nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko

àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú,

wọn yóò run láéláé.

8Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,

Olúwa,

nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;

gbogbo àwọn olùṣe búburú

ni a ó fọ́nká.

10Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;

òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.

11Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;

ìparun sí àwọn ènìyàn búburú

tí ó dìde sí mi.

12Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,

wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,

13tí a gbìn sí ilé Olúwa,

Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

14Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,

wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,

15láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;

òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú

kankan nínú rẹ̀.”

93

Saamu 93

1Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;

ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ

àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.

Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;

kò sì le è yí.

2Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;

ìwọ wà títí ayérayé.

3A ti gbé òkun sókè, Olúwa,

òkun ti gbé ohùn wọn sókè;

òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.

4Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,

ó ni ògo ju òkun rírú lọ

Olúwa ga ní ògo.

5Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;

ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́

fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

94

Saamu 94

1Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,

Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.

2Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;

san ẹ̀san fún agbéraga

ohun tí ó yẹ wọ́n.

3Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,

Olúwa

tí àwọn ẹni búburú

yóò kọ orin ayọ̀?

4Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;

gbogbo àwọn olùṣe búburú

kún fún ìṣògo.

5Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:

wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.

6Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,

wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.

7Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;

Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

8Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn;

ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?

Ẹni tí ó dá ojú?

Ó ha lè ṣe aláìríran bí?

10Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?

Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

1194.11: 1Kọ 3.20.Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;

ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

12Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí

ìwọ bá wí, Olúwa,

ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,

13Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,

títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀,

Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.

15Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,

àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn

dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.

16Ta ni yóò dìde fún mi

sí àwọn olùṣe búburú?

Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,

èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.

18Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,

Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

19Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,

ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ

ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?

21Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo

wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

22Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,

àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni

tí mo ti ń gba ààbò.

23Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn

yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn

Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

95

Saamu 95

1Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa,

ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.

2Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò

orin àti ìyìn.

3Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,

ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

4Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,

ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.

5Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a

àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,

ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú

Olúwa ẹni tí ó dá wa,

795.7-11: Hb 3.7-11; 4.3-11.nítorí òun ni Ọlọ́run wa,

àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,

àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,

àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,

9nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò

tí wọn wádìí mi,

tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.

10Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;

mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ

wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’

11Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi,

‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”

96

Saamu 96

196.1-13: 1Ki 16.23-33.Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀

ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.

3Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

4Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;

òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.

5Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè

ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

6Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀

agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

7Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,

ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa.

8Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;

ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.

9Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;

ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

10Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.”

A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;

ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo

jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.

12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;

nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.

13Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,

nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé

àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

97

Saamu 97

1Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀

jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.

2Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká

òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.

4Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé

ayé rí i ó sì wárìrì.

5Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,

níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

797.7: Hb 1.6.Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,

àwọn tí ń fi ère gbéraga,

ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

8Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn

inú àwọn ilé Juda sì dùn,

nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.

9Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ

ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.

10Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́

Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́

ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo

àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.

12Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,

kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

98

Saamu 98

1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀

o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

2Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀

o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.

3Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;

gbogbo òpin ayé ni ó ti rí

iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

4Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,

ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,

5ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

6pẹ̀lú ìpè àti fèrè

ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

7Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo

ohun tí ó wà nínú rẹ̀,

Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

8Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,

ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;

9ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa,

nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé

bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo

àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

99

Saamu 99

1Olúwa jẹ ọba;

jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì

Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù

jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.

2Olúwa tóbi ní Sioni;

Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.

3Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi

tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.

4Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,

ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;

ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.

5Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

6Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀

Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀

wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

7Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,

wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

8Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;

ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli

ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.

9Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀

nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

100

Saamu 100

Saamu. Fún ọpẹ́.

1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

2Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa,

ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

3Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,

kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé

tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀

àti àgùntàn pápá rẹ̀.

4Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;

ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

5Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore

ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;

àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

101

Saamu 101

Ti Dafidi. Saamu.

1Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;

sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.

2Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,

ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?

Èmi yóò máa rìn ní ilé mi

pẹ̀lú àyà pípé.

3Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:

iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.

Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

4Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;

èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,

òun ní èmi yóò gé kúrò

ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,

òun ní èmi kì yóò faradà fún.

6Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,

kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;

ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé

òun ni yóò máa sìn mí.

7Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,

kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

8Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ

gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;

èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú

kúrò ní ìlú Olúwa.

102

Saamu 102

Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa.

1Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,

jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.

2Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi

ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.

Dẹ etí rẹ sí mi;

nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.

3Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;

egungun mi sì jóná bí ààrò.

4Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;

mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.

5Nítorí ohùn ìkérora mi,

egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.

6Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:

èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.

7Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.

8Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;

àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.

9Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.

10Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.

11Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́

èmi sì rọ bí koríko.

12Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;

ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.

13Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,

nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;

àkókò náà ti dé.

14Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;

wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.

15Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,

gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.

16Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.

17Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;

kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,

àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

19Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá

láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,

20láti gbọ́ ìrora ará túbú,

láti tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”

21Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni

àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

22Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti

ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,

ó gé ọjọ́ mi kúrú.

24Èmi sì wí pé:

“Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.

25102.25-27: Hb 1.10-12.Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

26Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;

gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.

Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn

wọn yóò sì di àpatì.

27Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,

ọdún rẹ kò sì ní òpin.

28Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;

a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”

103

Saamu 103

Ti Dafidi.

1Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́

tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,

4ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú

ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

5ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn

kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún

gbogbo àwọn tí a ni lára.

7Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;

8103.8: Jk 5.11.Olúwa ni aláàánú àti olóore,

ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo

bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,

10Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa

bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́

bí àìṣedéédéé wa.

11Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn

bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

14nítorí tí ó mọ dídá wa,

ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,

ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó,

16afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,

kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.

17103.17: Lk 1.50.Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́

Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

18sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́

àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,

ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

tí ó ní ipá,

tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.

21Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,

ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní

ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

104

Saamu 104

1Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;

ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

2Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;

ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní,

3ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.

Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ

ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

4104.4: Hb 1.7.Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,

ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

5O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;

tí a kò le è mì láéláé.

6Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;

àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.

7Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,

nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.

8wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,

wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,

sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

9Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;

láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

10Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;

tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.

11Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi

àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.

12Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi

wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.

13Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;

a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

14Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ

àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò,

kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá.

15Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,

òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,

àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.

16Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,

kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.

17Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn

bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.

18Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;

àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

19Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò

oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.

20Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,

nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.

21Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn

wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

22Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,

wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.

23Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,

àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!

Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:

ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.

25Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,

tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye

ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.

26Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,

àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́

láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.

28Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,

wọn yóò kó jọ;

nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,

a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.

29Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́

ara kò rọ̀ wọ́n

nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,

wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.

30Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,

ni a dá wọn,

ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;

kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀,

32ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,

ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:

èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa

níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.

34Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn

bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.

35Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé

kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

105

Saamu 105

1105.1-15: 1Ki 16.8-22.Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

2Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;

sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

3Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4Olúwa àti ipá rẹ̀;

wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

5Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,

ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,

ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:

ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8105.8-9: Lk 1.72-73.Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,

ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,

9májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,

ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

10Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ,

sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:

11“Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani

gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

12Nígbà tí wọn kéré níye,

wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀

13wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,

láti ìjọba kan sí èkejì.

14Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;

ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

15“Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

16Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà

ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;

17Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn

Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18Wọn fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀

a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin,

19títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ

títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.

20Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀

àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀

21Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀,

aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa

ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé

kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23Israẹli wá sí Ejibiti;

Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.

24Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i

ó sì mú wọn lágbára jù

àwọn ọ̀tá wọn lọ

25Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn

láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

26Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀,

àti Aaroni tí ó ti yàn.

27Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn

ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.

28Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú

wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

ó pa ẹja wọn.

30Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,

èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,

ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn

32Ó sọ òjò di yìnyín,

àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;

33Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn

ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.

34Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,

àti kòkòrò ní àìníye,

35wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,

wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run.

36Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,

ààyò gbogbo ipá wọn.

37Ó mú Israẹli jáde

ti òun ti fàdákà àti wúrà,

nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,

nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,

àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́.

40Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,

ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.

41Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;

gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀

àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.

43Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde

pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀

44Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,

wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́

kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

106

Saamu 106

1106.1: 1Ki 16.34.Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún

Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun,

nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

2Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,

ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?

3Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?

Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

4Rántí mi, Olúwa,

nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,

wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,

5kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,

kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,

ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

6Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,

àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,

a sì ti hùwà búburú.

7Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,

iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,

wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,

gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.

8Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ

láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.

9O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;

o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.

10O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn,

láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.

11Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn;

bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.

12Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́

wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.

13Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe

wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.

14Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,

nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.

15Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún

ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose

pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

17Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì

ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.

18Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;

iná jo àwọn ènìyàn búburú.

19Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù

wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.

20Wọ́n pa ògo wọn dà

sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.

21Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n

ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,

22iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu

àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.

23Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run

bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,

tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà

tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

24Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà

wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.

25Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn

wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.

26Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè

kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,

27láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè

láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.

28Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,

wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,

29wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe

àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.

30Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,

àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.

31A sì ka èyí sí òdodo fún un àti

fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀

32Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,

ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.

33Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.

34Wọn kò pa àwọn ènìyàn run

gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,

35Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.

36Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn

tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.

37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ

àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

38Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ.

Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani,

ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

39Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,

wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀

ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀

41Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,

àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

42Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú

wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

43Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,

síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i

wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

44Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro

nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,

45ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn

Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.

46Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn

ó mú wọn rí àánú.

47106.47-48: 1Ki 16.35-36.Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,

kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,

láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ

láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48Olùbùkún ni Olúwa,

Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

107

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

Saamu 107

1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

2Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí,

àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

3àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,

láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,

láti àríwá àti Òkun wá.

4Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,

wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí

wọn ó máa gbé.

5Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,

ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.

6Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè

Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn

7Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú

tí wọn lè máa gbé.

8Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́

ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

9nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run

ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.

10Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,

a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,

11nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀

Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,

12Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;

wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí

yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13Ní ìgbà náà wọ́n ké pe

Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14Ó mú wọn jáde kúrò nínú

òkùnkùn àti òjìji ikú,

ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì

ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.

17Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn

wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

18Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ

wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.

19Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn,

ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.

20Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá

ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.

21Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

22Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́

kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

23Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi,

wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.

24Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.

25Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́

tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.

26Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì

tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:

nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.

27Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:

ọgbọ́n wọn sì dé òpin.

28Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè

Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.

29Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́

bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.

30Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,

ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.

31Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún

Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

32Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn

kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.

33Ó sọ odò di aginjù,

àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

34Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀

nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.

35O sọ aginjù di adágún omi àti

ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,

36níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,

wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.

37Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà

tí yóò máa so èso tí ó dára;

38Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye

kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.

39Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,

ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,

40ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé

ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.

41Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira

ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.

42Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn

ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

43Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí

kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

108

Saamu 108

Orin. Saamu ti Dafidi.

1108.1-5: Sm 57.7-11.Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin

èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.

2Jí ohun èlò orin àti haapu!

Èmi ó jí ní kùtùkùtù,

3èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.

4Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ

ju àwọn ọ̀run lọ

àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.

5Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,

àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

6108.6-13: Sm 60.5-12.Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;

fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,

kí o sì dá mi lóhùn

7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé,

“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,

èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.

8Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,

Efraimu ni ìbòrí mi,

Juda ni olófin mi,

9Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,

lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

10Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?

Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?

11Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.

Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.

12Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,

nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.

13Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin

nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

109

Saamu 109

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

1Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,

má ṣe dákẹ́,

2nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn

ti ya ẹnu wọn sí mi

wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.

3Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;

wọ́n bá mi jà láìnídìí

4Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,

ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.

5Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi

àti ìríra fún ìfẹ́ mi.

6Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ

jẹ́ kí àwọn olùfisùn

dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

7Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́

kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.

8109.8: Ap 1.20.Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú;

kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.

9Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba

kí aya rẹ̀ sì di opó.

10Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri

kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.

11Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní

jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.

12Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un

tàbí kí wọn káàánú lórí

àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.

13Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò

kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.

14Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí

ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa.

Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.

15Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa

kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16Nítorí kò rántí láti ṣàánú,

ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,

kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.

17Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:

bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.

18Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù

bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.

19Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara,

àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.

20Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;

àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

21Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,

ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ.

Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.

22Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,

àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

23Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,

mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.

24Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà

ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.

25109.25: Mt 27.39; Mk 15.29.Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;

nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

26Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;

gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.

27Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí

wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.

28Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre,

nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,

ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.

29Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú

kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.

30Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi

ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.

31Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní

láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.

110

Saamu 110

Ti Dafidi. Saamu.

1110.1: Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2.Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,

títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ

di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

2Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀

láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.

3Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá

ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,

láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

4110.4: Hb 5.6,10; 6.20; 7.11,15,21.Olúwa ti búra,

kò sì í yí ọkàn padà pé,

“Ìwọ ni àlùfáà,

ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

5Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni

yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

6Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,

yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;

yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

7Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:

nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.

111

Saamu 111

1Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,

ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

2Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.

3Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:

àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.

4Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:

Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.

5Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:

òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

6Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀

láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.

7Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;

gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.

8Wọ́n dúró láé àti láé,

ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.

9Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:

ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,

mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:

òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,

ìyìn rẹ̀ dúró láé.

112

Saamu 112

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,

tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

2Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:

ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.

3Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;

òdodo rẹ̀ sì dúró láé.

4Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:

olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.

5Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,

a sì wínni;

ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

6Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:

olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.

7Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:

ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

8Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,

títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

9112.9: 2Kọ 9.9.Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú,

nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;

ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

10Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,

yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:

èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

113

Saamu 113

1Ẹ máa yin Olúwa.

Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,

ẹ yin orúkọ Olúwa.

2Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti

ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

3Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀

orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

4Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,

àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.

5Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,

tí ó gbé ní ibi gíga.

6Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò

òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

7Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,

àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.

8Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé

àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.

9Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,

àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ẹ yin Olúwa.

114

Saamu 114

1Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,

ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè

2Juda wà ní ibi mímọ́,

Israẹli wà ní ìjọba.

3114.3: El 14.21; Jo 3.16.Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:

Jordani sì padà sẹ́yìn.

4Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti

òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

5Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?

Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

6Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,

àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

7Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;

ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu

8tí ó sọ àpáta di adágún omi,

àti òkúta-ìbọn di orísun omi.

115

Saamu 115

1Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,

ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,

fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

2Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,

níbo ni Ọlọ́run wa wà.

3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:

tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

4115.4-8: Sm 135.15-18.Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,

iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.

5Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,

wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

6Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:

wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn.

7Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,

wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.

8Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;

gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

9Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:

òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn

10Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:

òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

11Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:

òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;

yóò bùkún ilé Aaroni.

13115.13: If 11.18; 19.5.Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,

àti kékeré àti ńlá.

14Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,

ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.

15Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa

ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:

ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.

17Òkú kò lè yìn Olúwa,

tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.

18Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa

láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

116

Saamu 116

1Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;

ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.

2Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,

èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

3Okùn ikú yí mi ká,

ìrora isà òkú wá sórí mi;

ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.

4Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:

Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”

5Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;

Ọlọ́run wa kún fún àánú.

6Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́

nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

7Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,

nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

8Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi

kúrò lọ́wọ́ ikú,

ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,

àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

9nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa

ní ilẹ̀ alààyè.

10116.10: 2Kọ 4.13.Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,

“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.

11Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé,

“Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12Kí ni èmi yóò san fún Olúwa

nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

13Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè

èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

14Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa

ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15Iyebíye ní ojú Olúwa

àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

16Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;

èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;

ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ

èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.

18Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa

ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,

19nínú àgbàlá ilé Olúwa

ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.

Ẹ yin Olúwa.

117

Saamu 117

1117.1: Ro 15.11.Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.

2Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,

àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.

Ẹ yin Olúwa!

118

Saamu 118

1118.1: 1Ki 16.34; 2Ki 5.13; 7.3; Es 3.11; Sm 100.5; 106.1; 107.1; 136.1; Jr 33.11.Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;

àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2Jẹ́ kí Israẹli wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

3Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

4Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”

5Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,

ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

6118.6: Hb 13.6.Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.

Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

7Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi.

Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.

8Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

9Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.

10Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,

ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò.

11Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,

ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù.

12Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,

ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;

ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.

13Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,

ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.

14Olúwa ni agbára àti orin mi;

ó sì di ìgbàlà mi.

15Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:

“Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!

16Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;

ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”

17Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,

èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.

18Olúwa bá mi wí gidigidi,

ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:

èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

20Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa

ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.

21Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;

ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22118.22-23: Mt 21.42; Mk 12.10-11; Lk 20.17; Ap 4.11; 1Pt 2.7.Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,

ni ó di pàtàkì igun ilé;

23Olúwa ti ṣe èyí,

ó ṣe ìyanu ní ojú wa.

24Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:

ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

25118.25-26: Mt 21.9; 23.39; Mk 11.9-10; Lk 13.35; 19.38; Jh 12.13.Olúwa, gbà wá;

Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.

26Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.

Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.

27Olúwa ni Ọlọ́run,

ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára

pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́

ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀

ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.

28Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;

ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.

29Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

119

Saamu 119

1Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,

ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.

2Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́

tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

3Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;

wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

4Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀

kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

5Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin

láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!

6Nígbà náà, ojú kò ní tì mí

nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.

7Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin

bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.

8Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀,

má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.

9Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?

Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.

10Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi

má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.

11Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi

kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.

12Ìyìn ni fún Olúwa;

kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

13Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò

gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.

14Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,

bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.

15Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ

èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.

16Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;

èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.

17Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;

èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.

18La ojú mi kí èmi lè ríran rí

ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.

19Àlejò ní èmi jẹ́ láyé,

má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.

20Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà

nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.

21Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún

tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.

22Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,

nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.

23Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀,

wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,

ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.

24Òfin rẹ ni dídùn inú mi;

àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.

25Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;

ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

26Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;

kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

27Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:

nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.

28Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;

fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

29Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn

fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.

30Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́

èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.

31Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa

má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

32Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,

nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

33Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;

nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́

èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.

35Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,

nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

36Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ

kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.

37Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:

pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

38Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,

nítorí òfin rẹ dára.

39Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù

nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.

40Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!

Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.

41Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,

ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.

42Nígbà náà ni èmi yóò dá

ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,

nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

43Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi

nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.

44Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo

láé àti láéláé.

45Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,

nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.

46Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba

ojú kì yóò sì tì mí,

47nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ

nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.

48Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,

èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

49Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,

nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.

50Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:

ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.

51Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,

ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.

52Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,

èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.

53Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,

tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.

54Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi

níbikíbi tí èmi ń gbé.

55Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,

èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́

56nítorí tí mo

gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.

57Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:

èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.

58Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:

fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.

59Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi

èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.

60Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra

láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.

61Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,

èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.

62Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ

nítorí òfin òdodo rẹ.

63Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.

64Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa,

kọ́ mi ní òfin rẹ.

65Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ

gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.

66Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,

nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.

67Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,

ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.

68Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;

kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

69Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,

èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

70Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,

ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.

71Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú

nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.

72Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ

ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.

73Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;

fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.

74Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,

nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

75Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,

àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

76Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,

gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.

77Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,

nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.

78Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga

nítorí wọn pa mí lára láìnídìí

ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.

79Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,

àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.

80Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,

kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

81Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,

ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

82Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;

èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”

83Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,

èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.

84Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?

Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn

tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?

85Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,

tí ó lòdì sí òfin rẹ.

86Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé;

ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.

87Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,

ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.

88Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,

èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.

89Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;

ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.

90Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;

ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.

91Òfin rẹ dúró di òní

nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.

92Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,

èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.

93Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,

nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.

94Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ

èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.

95Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,

ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.

96Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;

ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.

97Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!

Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀

ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

98Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,

nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.

99Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,

nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.

100Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,

nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi

nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.

102Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,

nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.

103Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,

ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!

104Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;

nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

105Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi

àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.

106Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn

wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.

107A pọ́n mi lójú gidigidi;

Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ

108Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,

kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.

109Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo,

èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.

110Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,

ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.

111Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;

àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.

112Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́

láé dé òpin.

113Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,

ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.

114Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;

èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

115Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,

kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!

116Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,

kí èmi kí ó lè yè

Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

117Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;

nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.

118Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,

nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

119Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;

nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.

120Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:

èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.

121Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:

má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:

má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

123Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,

fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.

124Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ

kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

125Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye

kí èmi lè ní òye òfin rẹ

126Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;

nítorí òfin rẹ ti fọ́.

127Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ

ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

128nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,

èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

129Òfin rẹ̀ ìyanu ni:

nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;

ó fi òye fún àwọn òpè.

131Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,

nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.

132Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,

bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn

tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.

133Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,

má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

134Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,

kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.

135Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára

kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

136Omijé sàn jáde ní ojú mi,

nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137Olódodo ni ìwọ Olúwa

ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.

138Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:

wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139Ìtara mi ti pa mí run,

nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.

140Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá

ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

141Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn

èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.

142Òdodo rẹ wà títí láé

òtítọ́ ni òfin rẹ̀.

143Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,

ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.

144Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;

fún mi ní òye kí èmi lè yè.

145Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:

dá mi lóhùn Olúwa,

èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.

146Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí

èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.

147Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;

èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

148Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,

nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.

149Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:

pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.

150Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,

ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.

151Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,

àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.

152Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ

tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,

nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.

154Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;

pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.

155Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú

nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.

156Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;

pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.

157Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,

ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.

158Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́

nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.

159Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;

pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.

160Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;

gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.

161Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,

ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.

162Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ

bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe

ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.

164Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́

nítorí òfin òdodo rẹ.

165Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,

kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,

èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.

167Èmi gba òfin rẹ gbọ́,

nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.

168Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,

nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

169Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;

fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

170Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;

gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.

171Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,

nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

172Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,

nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.

173Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,

nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.

174Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,

àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.

175Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,

kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.

176Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù.

Wá ìránṣẹ́ rẹ,

nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

120

Saamu 120

Orin fún ìgòkè.

1Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,

ó sì dá mi lóhùn.

2Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké

àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

3Kí ni kí a fi fún ọ?

Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,

ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?

4Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,

pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

5Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,

nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!

6Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé

láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.

7Ènìyàn àlàáfíà ni mí;

ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

121

Saamu 121

Orin fún ìgòkè.

1Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—

níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

2Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

3Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;

ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

4Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,

kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

5Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;

Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

6Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán

tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

7Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo

yóò pa ọkàn rẹ mọ́

8Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́

láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

122

Saamu 122

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,

“Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”

2Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,

ìwọ Jerusalẹmu.

3Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú

tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.

4Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,

àwọn ẹ̀yà Olúwa,

ẹ̀rí fún Israẹli,

láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.

5Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,

àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

6Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;

àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

7Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,

àti ìre nínú ààfin rẹ̀.

8Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi

èmi yóò wí nísinsin yìí pé,

kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.

9Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,

èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

123

Saamu 123

Orin fún ìgòkè.

1Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,

ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.

2Kíyèsi, bí ojú àwọn

ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,

àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,

títí yóò fi ṣàánú fún wa.

3Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;

nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.

4Ọkàn wa kún púpọ̀

fún ẹ̀gàn àwọn onírera,

àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

124

Saamu 124

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1“Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”

kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

2ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,

nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

3nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè

nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

4nígbà náà ni omi

wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

5nígbà náà ni agbéraga

omi ìbá borí ọkàn wa.

6Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n

bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

7Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;

okùn já àwa sì yọ.

8Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,

tí ó dá ọ̀run òun ayé.

125

Saamu 125

Orin fún ìgòkè.

1Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,

tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.

2Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká

láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

3Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú

kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;

kí àwọn olódodo kí ó máa ba à

fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

4Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,

àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.

5Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;

Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

126

Saamu 126

Orin fún ìgòkè.

1Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,

àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.

2Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,

àti ahọ́n wa kọ orin;

nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,

Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

3Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;

nítorí náà àwa ń yọ̀.

4Olúwa mú ìkólọ wa padà,

bí ìṣàn omi ní gúúsù.

5Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn

yóò fi ayọ̀ ka.

6Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,

tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,

lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,

yóò sì ru ìtí rẹ̀.

127

Saamu 127

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

1Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà

àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;

bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

2Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù

láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;

bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

3Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:

ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.

4Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.

5Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;

ojú kì yóò tì wọ́n,

ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

128

Saamu 128

Orin fún ìgòkè.

1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:

tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ

ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere

eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;

àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,

tí ó bẹ̀rù Olúwa.

5Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,

kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre

Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

6Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.

Láti àlàáfíà lára Israẹli.

129

Saamu 129

Orin fún ìgòkè.

1“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú

láti ìgbà èwe mi wá,”

jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;

2“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú

láti ìgbà èwe mi wá;

síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.

3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:

wọ́n sì la aporo wọn gígùn.

4Olódodo ni Olúwa:

ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”

5Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,

kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.

6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀

tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè,

7èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.

8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,

ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:

àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

130

Saamu 130

Orin fún ìgòkè.

1Láti inú ibú wá ni

èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa

2Olúwa, gbóhùn mi,

jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3130.3: Sm 143.2; Ro 3.20; Ga 2.16.Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,

Olúwa, tá ni ìbá dúró.

4Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,

kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

5Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,

àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.

6Ọkàn mi dúró de Olúwa,

ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,

àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

7Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:

nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,

àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.

8Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè

kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

131

Saamu 131

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1Olúwa àyà mi kò gbéga,

bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:

bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,

tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

2Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,

mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,

bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:

ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.

3Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa

láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.

132

Saamu 132

Orin fún ìgòkè.

1Olúwa, rántí Dafidi

nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

2Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,

tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.

3Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,

bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.

4Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,

tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

5títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,

ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.

6Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:

àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

7Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:

àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀

8Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:

ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.

9Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:

kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

10Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀,

má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

11132.11: Sm 89.3-4; Ap 2.30.Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi,

Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,

nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

12Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́

àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,

àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

13Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:

ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.

14Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:

níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:

nítorí tí mo fẹ́ ẹ.

15Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:

èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.

16Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:

àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

17Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,

èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.

18Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:

ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.

133

Saamu 133

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún

àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

2Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,

tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:

tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀.

3Bí ìrì Hermoni

tí o sàn sórí òkè Sioni.

Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,

àní ìyè láéláé.

134

Saamu 134

Orin ìgòkè.

1Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,

gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,

tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.

2Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,

kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.

3Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,

kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.

135

Saamu 135

1Ẹ yin Olúwa.

Ẹ yin orúkọ Olúwa;

ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.

2Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,

nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.

3Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;

ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.

4Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;

àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.

5Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,

àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.

6Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,

ní ọ̀run àti ní ayé,

ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.

7Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:

ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:

ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.

8Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,

àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.

9Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,

sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.

10Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,

tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.

11Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,

ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:

12Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.

13Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;

ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.

14135.14: Hb 10.30.Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,

yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

15Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,

iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.

16Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;

wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

17Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;

bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn.

18Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:

gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

19Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,

ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.

20Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;

ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.

21Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,

tí ń gbé Jerusalẹmu.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

136

Saamu 136

1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

3Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

4Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

5Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

6136.6: Gẹ 1.2.Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

7136.7-9: Gẹ 1.16.Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

8Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

9Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

10136.10: Ek 12.29.Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

11136.11: Ek 12.51.Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

12Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

13136.13-15: Ek 14.21-29.Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

14Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

15Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

16Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

17Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

18Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

19Sihoni, ọba àwọn ará Amori

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

20Àti Ogu, ọba Baṣani;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

21Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

22Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

23Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

24Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

25Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

26Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

137

Saamu 137

1Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó

àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

2Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,

tí ó wà láàrín rẹ̀.

3Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn

tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,

àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;

wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

4Àwa ó ti ṣe kọ orin

Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

5Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ

jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

6Bí èmi kò bá rántí rẹ,

jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;

bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú

olórí ayọ̀ mi gbogbo.

7Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,

lára àwọn ọmọ Edomu,

àwọn ẹni tí ń wí pé,

“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”

8Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;

ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ

bí ìwọ ti rò sí wa.

9Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ

tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

138

Saamu 138

Ti Dafidi.

1Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;

níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.

2Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀

èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ

nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;

nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.

3Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,

ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

4Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,

Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

5Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;

nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

6Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;

ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.

7Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;

ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,

ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.

8Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;

Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;

má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

139

Saamu 139

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

1Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,

ìwọ sì ti mọ̀ mí.

2Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,

ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.

3Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,

gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.

4Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,

kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.

5Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,

ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.

6Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;

ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

7Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?

Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?

8Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;

bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,

kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

9Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,

kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,

10àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí

ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.

11Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;

kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”

12Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;

ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;

àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

13Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;

ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

14Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;

ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;

èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.

15Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.

Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

16ojú rẹ ti rí ohun ara mi

nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,

àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,

ní ọjọ́ tí a dá wọn,

nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

17Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,

iye wọn ti pọ̀ tó!

18Èmi ìbá kà wọ́n,

wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:

nígbà tí mo bá jí,

èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

19Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;

nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.

20Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,

àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!

21Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?

Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

22Èmi kórìíra wọn ní àkótán;

èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.

23Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;

dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.

24Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú

kan bá wà nínú mi kí ó sì

fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

140

Saamu 140

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,

yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,

2ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;

nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.

3Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,

oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

4Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;

yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì

ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.

5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:

wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;

wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

6Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;

Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,

ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

8Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;

má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;

kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.

9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,

jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.

10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára,

Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,

sínú ọ̀gbun omi jíjìn,

kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.

11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;

ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,

yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.

13Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò

máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;

àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.

141

Saamu 141

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.

Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.

2Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí

àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.

3Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:

kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.

4Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,

láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú

má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.

5Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́:

jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.

Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.

Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.

6A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,

àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.

7Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”

8Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;

nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.

9Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,

kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

10Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,

nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

142

Saamu 142

Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.

1Èmi kígbe sókè sí Olúwa;

èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.

2Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

3Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,

ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.

Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn

ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.

4Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i

kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi

èmi kò ní ààbò;

kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

5Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:

èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi,

ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

6Fi etí sí igbe mi,

nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí

gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,

nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.

7Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,

kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.

Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri

nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

143

Saamu 143

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa gbọ́ àdúrà mi,

fetísí igbe mi fún àánú;

nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.

2143.2: Sm 130.3; Ro 3.20; Ga 2.16.Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,

nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè

tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.

3Ọ̀tá ń lépa mi,

ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;

ó mú mi gbé nínú òkùnkùn

bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.

4Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;

ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.

5Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;

èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ

mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.

6Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:

òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

7Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;

ó rẹ ẹ̀mí mi tán.

Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi

kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.

8Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:

nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,

nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.

9Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,

nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.

10Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,

nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi

jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára

darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

11Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;

nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.

12Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,

run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,

nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.

144

Saamu 144

Ti Dafidi.

1Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,

ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,

àti ìka mi fún ìjà.

2Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,

ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,

ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,

ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.

3Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,

tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?

4Ènìyàn rí bí èmi;

ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

5Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;

tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.

6Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;

ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.

7Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;

gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu

kúrò nínú omi ńlá:

kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.

8Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké

ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

9Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ

Ọlọ́run; lára ohun èlò orin

olókùn mẹ́wàá èmi yóò

kọ orin sí ọ.

10Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,

ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.

Lọ́wọ́ pípanirun. 11Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu

kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì

tí ẹnu wọn kún fún èké,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12Kí àwọn ọmọkùnrin wa

kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,

àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé

tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

13Àká wa yóò kún

pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ

àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,

ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

14àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo

kí ó má sí ìkọlù,

kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,

kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

15Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,

ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,

tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

145

Saamu 145

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

1Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;

èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.

2Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́

èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

3Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:

kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.

4Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;

wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ.

5Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,

èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.

6Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù

èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.

7Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀

ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

8Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú

ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

9Olúwa dára sí ẹni gbogbo;

ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.

10Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni

yóò máa yìn ọ́ Olúwa;

àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.

11Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ

wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,

12kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀

àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.

13Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,

àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.

14Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró

ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

15Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,

ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ.

16Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ

ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀

àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

18Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,

sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

19Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;

ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

20Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí

ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni

búburú ní yóò parun.

21Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.

Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

146

Saamu 146

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

2Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi,

èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.

3Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,

àní, ọmọ ènìyàn,

lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,

ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

5Ìbùkún ni fún ẹni tí

Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀

tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,

òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,

ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

7Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára,

tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,

Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,

8Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,

Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,

Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

9Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò

ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí

ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10Olúwa jẹ ọba títí láé;

Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

147

Saamu 147

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,

ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

2Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;

Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.

3Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn

ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.

4Ó ka iye àwọn ìràwọ̀

ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.

5Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára

òye rẹ̀ kò sì ní òpin.

6Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

7Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa

fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

8Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀

ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé

ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

9Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko

àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,

bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

11Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

12Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu;

yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,

Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ

14Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,

òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.

16Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn

ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú

17Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́

ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀

18Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀

ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́

ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu

àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.

20Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀

wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

148

Saamu 148

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,

ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.

2Ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

3Ẹ fi ìyìn fún un,

oòrùn àti òṣùpá.

Ẹ fi ìyìn fún un,

gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

4Ẹ fi ìyìn fún un,

ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga

àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

5Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

6Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé

ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

7Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá

ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi

àti ẹ̀yin ibú òkun,

8mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín

ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,

ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

9òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké,

igi eléso àti gbogbo igi kedari,

10àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn

gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,

11àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo

àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,

12ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin

àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá

ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

14Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,

ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,

àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

149

Saamu 149

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.

Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

2Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a

jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní

ayọ̀ nínú ọba wọn.

3Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀

jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

4Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀

ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀

kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

6Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn

àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.

7Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,

àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,

8láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn

àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀

irin de àwọn ọlọ́lá wọn.

9Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn

èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

150

Saamu 150

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,

ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.

2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.

Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.

3Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.

Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.

4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín

fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,

5Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,

ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

6Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.