Ìwé Òwe

1

Èròǹgbà àti kókó-ọ̀rọ̀

1Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.

2Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,

láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.

3Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,

àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;

4láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,

ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.

5Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,

sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.

6Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,

àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.

7Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ṣàfẹ́rí ọgbọ́n

8Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,

má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.

9Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ

àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.

10Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,

má ṣe gbà fún wọn.

11Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;

jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,

jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

12jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,

àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

13a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí

a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,

14da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,

a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”

15ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,

má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.

16Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,

wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

17Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀,

ní ojú ẹyẹ!

18Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.

Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà.

19Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;

yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.

Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀

201.20,21: Òw 8.1-3.Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó

ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;

21láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde

ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

22“Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?

Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?

Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?

23Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,

ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín

kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.

24Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè

kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

25níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,

tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

26Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;

èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.

27Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,

nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,

nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

28“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;

wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

29Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀

tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.

30Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi

tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,

31wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn

wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.

32Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n

ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;

33ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu

yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

2

Èrè ìwà rere tí ọgbọ́n ń mú wá

1Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,

tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

2tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n

tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,

3àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,

tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye

4bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà

tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.

5Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,

ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

6Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,

láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

7Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,

Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

8Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́

Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

9Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,

àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.

10Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ

ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.

11Ìmòye yóò pa ọ mọ́

òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.

12Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,

lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,

13ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin

láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,

14ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,

tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,

15ọ̀nà ẹni tí ó wọ́

tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.

16Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,

àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,

17ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀

tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.

18Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú

ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.

19Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà

bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.

20Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere

kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.

21Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà

àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.

22Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà

a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.

3

Àwọn àǹfààní ọgbọ́n mìíràn

1Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.

Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

2Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,

ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.

3Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé

so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,

kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.

43.4: Ro 12.17.Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere

ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

5Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ

má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

6Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ

òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

73.7: Ro 12.16.Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ

bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

8Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ

àti okun fún àwọn egungun rẹ.

9Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,

pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,

10nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya

àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.

113.11,12: Hb 12.5,6.Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa

má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,

12nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí

bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

13Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,

ẹni tí ó tún ní òye sí i,

14nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ

ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;

kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,

òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;

àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

19Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;

20nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,

àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

21Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,

má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

22Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,

àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

23Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,

ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

24Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,

nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.

25Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,

tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

26Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,

kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

27Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,

nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

28Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,

“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”

nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.

29Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,

ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.

30Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,

nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

31Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan

tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

32Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà

ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.

33Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.

343.34: (Gk): Jk 4.6; 1Pt 5.5.Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,

ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.

35Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,

ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.

4

Ọgbọ́n ni o ga jùlọ

1Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.

2Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro,

nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.

3Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,

mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.

4Ó kọ́ mi ó sì wí pé,

“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,

pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.

5Gba ọgbọ́n, gba òye,

má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.

6Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,

fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.

7Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.

Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.

8Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga

dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

9Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ

yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,

ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

11Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n

mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.

12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́

nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.

13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;

tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.

14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú

tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;

yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.

16Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,

wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.

17Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú

wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

18Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn

tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí

19ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;

wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

20Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;

fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.

21Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú

pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,

22nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn

àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.

23Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́,

nítorí òun ni orísun ìyè.

24Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;

sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.

25Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,

jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.

264.26: (Gk): Hb 12.13.Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ

sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.

27Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;

pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.

5

Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè

1Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,

kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,

2kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra

kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.

3Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.

4Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,

ó mú bí idà olójú méjì.

5Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú

ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.

6Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;

ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.

7Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,

kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.

8Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,

má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀,

9àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́

àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.

10Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,

kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.

11Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,

nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.

12Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!

Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!

13N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,

tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.

14Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá

ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15Mu omi láti inú kànga tìrẹ,

omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.

16Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà

àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?

17Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,

má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.

18Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;

kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.

19Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,

jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,

kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.

20Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,

tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?

21Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa

Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò.

22Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;

okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.

23Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́

ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.

6

Ìkìlọ̀ láti ṣọ́ra fún ìwà òmùgọ̀

1Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,

bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn,

2bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,

tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté.

3Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ

níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:

lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;

bẹ aládùúgbò rẹ dáradára.

4Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,

tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.

5Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,

bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.

6Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;

kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

7Kò ní olùdarí,

kò sí alábojútó tàbí ọba,

8síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò

yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

9Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?

Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?

10Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,

ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀.

11Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà

àti àìní bí adigunjalè.

12Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú,

tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,

13tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò,

ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀

ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,

14tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀

ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.

15Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn;

yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

16Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,

ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

17Ojú ìgbéraga,

ahọ́n tó ń parọ́

ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

18ọkàn tí ń pète ohun búburú,

ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

19ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu

àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

Ìkìlọ̀ nítorí àgbèrè

20Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́

má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

21Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé

so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

22Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;

nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;

nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.

23Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,

ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,

àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí

ni ọ̀nà sí ìyè.

24Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,

kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.

25Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ

tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.

26Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,

ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.

27Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan

kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?

28Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?

Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?

29Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;

kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.

30Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè

nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.

31Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje

bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.

32Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú;

ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni.

33Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,

ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.

34Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,

kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.

35Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn;

yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.

7

Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó

1Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,

sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.

2Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè

tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.

3Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun

kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.

4Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”

sì pe òye ní ìbátan rẹ.

5Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,

kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.

6Ní ojú fèrèsé ilé è mi

mo wo ìta láti ojú fèrèsé.

7Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan

mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,

ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.

8Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,

ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.

9Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,

bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.

10Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,

ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.

11(Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,

ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;

12bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún

gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)

13Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu

pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,

14“Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;

lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

15Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;

mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

16Mo ti tẹ́ ibùsùn mi

pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.

17Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi

bí i òjìá, aloe àti kinamoni.

18Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;

jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

19Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;

ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.

20Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́

kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

21Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;

ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

22Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,

bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa,

tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.

23Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,

bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,

láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

24Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi

fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

25Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,

tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀.

Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

27Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,

tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.

8

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

18.1-3: Òw 1.20,21.Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?

Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?

2Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,

ní ìkóríta, ní ó dúró;

3ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,

ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:

4“Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;

mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.

5Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;

ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.

6Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;

Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,

7ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,

nítorí ètè mi kórìíra ibi.

8Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,

kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.

9Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;

wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.

10Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,

ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,

11nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,

kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

12“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;

mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

13Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi

mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,

ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

14Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi

mo ní òye àti agbára.

15Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso

tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.

16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,

àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,

àwọn tí ó sì wá mi rí mi.

18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,

ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;

ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,

ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi

mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22“Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.

Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23a ti yàn mí láti ayérayé,

láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

24Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi,

nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;

25kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,

ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,

26kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀

tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.

27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,

nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,

28nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè

tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,

29nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun

kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,

àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀

mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,

mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.

31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá

mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,

ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.

33Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;

má ṣe pa á tì sápá kan.

34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,

tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,

tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.

35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè

ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.

36Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára

gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

9

Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n

1Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,

ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,

2ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.

Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀

3ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,

láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.

4“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”

Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,

5“Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi

sì mu wáìnì tí mo ti pò.

6Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;

rìn ní ọ̀nà òye.

7“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù

ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.

8Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.

Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

9kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i

kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

10“Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,

ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.

11Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.

12Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:

bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

13Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;

ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.

14Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀

lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,

15ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,

tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.

16“Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”

Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.

17“Omi tí a jí mu dùn

oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”

18Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,

pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.

10

Àwọn òwe Solomoni

1Àwọn òwe Solomoni.

Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

2Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,

ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

3Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo,

ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

4Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,

ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.

5Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

6Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo,

ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

7Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún,

ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,

ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,

ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn,

aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,

ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,

ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,

ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,

ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn,

ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

18Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́

ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

19Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù

ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

20Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,

ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.

21Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

22Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,

kì í sì í fi ìdààmú sí i.

23Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú,

ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

24Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;

olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,

ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,

ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28Ìrètí olódodo ni ayọ̀,

ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

29Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,

ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

30A kì yóò fa olódodo tu láéláé,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,

ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,

ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

11

1Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké,

ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.

2Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé,

ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

3Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀,

ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.

4Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú,

ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

5Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn,

ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.

6Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là,

ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.

7Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun;

gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.

8A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀,

ibi wá sórí ènìyàn búburú.

9Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.

10Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀;

nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

11Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga:

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

12Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

13Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀

ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.

14Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú

ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

15Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.

16Obìnrin oníwà rere gba ìyìn

ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore

ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ

ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

19Olódodo tòótọ́ rí ìyè

ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.

20Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú

ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.

21Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà,

ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.

22Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀

ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

23Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere

ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.

24Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;

òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.

25Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;

ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.

26Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́

ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

27Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere

ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

28Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;

ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

29Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán

aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.

30Èso òdodo ni igi ìyè

ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

3111.31: (Gk): 1Pt 4.18.Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé

mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!

12

1Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.

2Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa

ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.

3A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú

ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.

4Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀

ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.

5Èrò àwọn olódodo tọ́,

ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.

6Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.

7A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;

ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.

8A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀

ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.

9Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́

ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.

10Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,

ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.

11Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,

ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.

12Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà

ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.

13A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀

ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.

14Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere

bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.

15Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀

ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.

16Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,

ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.

17Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí

ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.

18Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀

ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.

19Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé

ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.

20Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú

ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.

21Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.

22Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́

ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.

23Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀

ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.

24Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba

ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.

25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́

ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.

27Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ

ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.

28Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà

ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.

13

1Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

2Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere,

ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.

3Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

4Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,

ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

5Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

6Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,

ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

7Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan

ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

8Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀

ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

9Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,

ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni

ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,

ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

12Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀

ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,

tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

15Òye pípé ń mú ni rí ojúrere,

ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀,

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú

ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.

18Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn

ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n

ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,

ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,

ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá

ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

25Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn

ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

14

1Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,

ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.

2Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,

ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

3Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

4Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní,

ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

5Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni

ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

6Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,

ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

7Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,

nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

8Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn

ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.

9Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀

ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

10Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀

kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11A ó pa ilé ènìyàn búburú run,

ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.

12Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,

ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.

13Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;

ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.

14A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,

ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

15Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́

ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

16Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.

17Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,

a sì kórìíra eléte ènìyàn.

18Òpè jogún ìwà òmùgọ̀

ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.

19Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere

àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.

20Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀,

ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.

21Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀

ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.

22Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?

Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.

23Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,

ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.

24Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn

ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.

25Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là

ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.

26Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,

yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,

tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

28Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,

ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.

29Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,

ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.

30Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,

ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.

31Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.

32Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,

kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.

33Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye

kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.

34Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,

ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.

35Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n

ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.

15

1Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

2Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde

ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

3Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,

Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

4Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè

ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

5Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

6Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,

ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

7Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;

ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

8Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú

ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.

9Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

10Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,

ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

11Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa,

mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.

12Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí:

kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

13Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká

ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.

14Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀

ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.

15Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,

ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.

16Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà

ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

17Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà

sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.

18Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀

ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

19Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí,

ṣùgbọ́n ọ̀nà olódodo já geerege ni.

20Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;

ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

22Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;

ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà.

23Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ

ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

24Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n

láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.

25Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀,

ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.

26Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.

27Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.

28Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò

ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

29Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú

ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

30Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,

ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.

31Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,

yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

32Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.

33Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,

ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

16

1Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn

ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀

ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.

3Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́,

èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.

4Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́

kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

5Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀

mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

6Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀

nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

7Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,

yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.

8Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo

ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.

9Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀

ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

10Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i

ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.

11Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;

gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́

nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,

wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.

14Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́

ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;

ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ

àti láti yan òye dípò o fàdákà!

17Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,

ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

18Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,

agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.

19Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú

jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

20Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,

ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

21Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye

ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.

22Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,

ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.

23Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀

ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.

24Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin

ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

25Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn

ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.

26Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀;

nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.

27Ènìyàn búburú ń pète

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.

28Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀

olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.

29Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀

ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

30Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;

ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.

31Adé ògo ni ewú orí jẹ́,

ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.

32Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,

ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.

33A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,

ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

17

1Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn

ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

2Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,

yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.

3Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà,

ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.

4Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi;

òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,

ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.

6Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó,

ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.

7Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè,

bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!

8Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í,

ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.

9Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.

Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.

10Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn

ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.

11Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,

ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.

12Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ

jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

13Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre,

ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.

14Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi;

nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

15Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi,

Olúwa kórìíra méjèèjì.

16Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,

níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?

17Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,

arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.

18Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,

ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;

ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.

20Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,

ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.

21Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn,

kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.

22Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,

ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.

23Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀

láti yí ìdájọ́ po.

24Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú,

ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.

25Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀

àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.

26Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀,

tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.

27Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,

ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.

28Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́,

àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.

18

1Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;

ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.

2Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye

ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.

3Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,

nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.

4Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,

ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.

5Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú

tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.

6Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀

ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

7Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,

ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.

8Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;

wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

9Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀

arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.

10Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;

olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

11Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;

wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

12Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,

ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

13Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,

èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.

14Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,

ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.

15Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;

etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.

16Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn

a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.

17Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre,

títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.

18Ìbò dídì máa ń parí ìjà

a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.

19Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,

ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.

20Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;

láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

21Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,

àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.

22Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,

o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.

23Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,

ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.

24Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,

ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.

19

1Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù

ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

2Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀,

tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.

3Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;

síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

4Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;

ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,

ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

6Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;

gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

7Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,

mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!

Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,

kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.

8Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;

ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà

ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,

mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.

11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;

fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,

ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,

aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,

ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.

15Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,

ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá,

yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;

àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.

19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;

bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.

20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,

ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;

ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.

23Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;

nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

24Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;

kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

25Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;

bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

26Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde

òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.

27Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,

tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

28Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,

ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.

29A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;

àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.

20

1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle;

ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.

2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún;

ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà,

ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,

nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

5Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn;

ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn,

ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.

7Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù

ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

8Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́

yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

9Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,

mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ

Olúwa kórìíra méjèèjì.

11Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀

nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran

Olúwa ni ó dá méjèèjì.

13Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.

Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

14“Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí;

nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán,

yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.

15Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ,

ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.

16Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;

mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

17Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn,

ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.

18Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn

bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.

19Olófòófó a máa tú àṣírí

nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.

20Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,

ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

21Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀

kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

22Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.”

Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

23Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké.

Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

24Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn.

Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?

25Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá

nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

26Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;

Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

27Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn

a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

28Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,

nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

29Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn,

ewú orí ni iyì arúgbó.

30Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,

pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

21

1Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;

a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.

2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀,

ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.

3Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà

ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.

4Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,

ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

5Ètè àwọn olóye jásí èrè

bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.

6Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́

jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.

7Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,

nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.

8Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀

ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.

9Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé

ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.

10Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi

aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

11Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn,

òpè a máa kọ́gbọ́n,

nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.

12Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú

ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.

Ìṣúra ẹni tí o gbọ́n

13Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,

òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;

ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.

14Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:

àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,

dẹ́kun ìbínú líle.

15Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:

ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

16Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,

yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.

17Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà:

ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.

18Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo,

àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin.

19Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú

oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.

20Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;

ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.

21Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,

òdodo, àti ọlá.

22Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,

ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.

23Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,

ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

24Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,

àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀.

25Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;

nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.

26Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:

ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.

27Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:

mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi?

28Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.

29Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:

ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

30Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,

tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.

31A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:

ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.

22

Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ

1Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,

àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.

2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:

Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.

3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,

ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:

ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.

4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.

5Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:

ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.

6Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:

nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.

7Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,

ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.

822.8: (Gk): 1Kọ 9.7.Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:

ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

9Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;

nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.

10Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;

nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.

11Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,

tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.

12Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,

ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.

13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!

Yóò pa mí ní ìgboro!”

14Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;

ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.

15Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;

ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

16Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,

tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,

yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.

Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n

17Dẹtí rẹ sílẹ̀,

kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,

kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.

18Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;

nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.

19Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,

èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.

20Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára

sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,

21kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;

kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́

fún àwọn tí ó rán ọ?

22Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:

bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,

23nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn,

yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.

24Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;

má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.

25Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.

26Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,

tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.

27Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,

nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?

28Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,

tí àwọn baba rẹ ti pa.

29Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?

Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;

òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.

23

Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun àdídùn

1Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,

kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.

2Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,

bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

3Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:

nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

4Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:

ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.

5Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?

Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀,

ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

6Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́,

bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.

7Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:

“Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;

ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.

8Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,

ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

9Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè;

nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò;

má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.

11Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;

yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

12Fi àyà sí ẹ̀kọ́,

àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

13Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,

nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.

14Bí ìwọ fi pàṣán nà án,

ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ọmọ rere

15Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,

ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.

16Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.

17Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,

ní ọjọ́ gbogbo.

18Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;

ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

19Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,

kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.

20Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;

àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

21nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà;

ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

22Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,

má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.

23Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;

ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.

24Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:

ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,

yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

25Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,

sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

26Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,

kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.

27Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni;

àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.

28Òun á sì ba ní bùba bí olè,

a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.

29Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?

Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

30Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì;

àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

31Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n,

nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,

tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

32Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò,

a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

33Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,

àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.

34Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun,

tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

35Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;

wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:

nígbà wo ni èmi ó jí?

Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”

24

1Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú

má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;

2nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,

ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

3Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́

nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;

4nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún

pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

5Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,

ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.

6Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:

nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

7Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè

àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

8Ẹni tí ń pète ibi

ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.

9Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,

àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú

báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!

11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;

fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.

12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”

ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?

Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,

oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.

14Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ

bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ

ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.

15Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú

láti gba ibùjókòó olódodo,

má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;

16nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni,

ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;

nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.

18Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú

yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi

tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,

20nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú

a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

21Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,

má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.

22Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,

ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn

23Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:

láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.

24Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,”

àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.

25Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,

ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26Ìdáhùn òtítọ́

dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.

27Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ

sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;

lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,

tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.

29Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;

Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,

mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;

31ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,

koríko ti gba gbogbo oko náà.

32Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi

mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;

33oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,

ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,

34òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè

àti àìní bí olè.

25

Àwọn òwe mìíràn ti Solomoni

1Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.

2Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;

láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

3Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì

bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

4Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà

ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.

5Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba

a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

6Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,

má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,

7ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,”

ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

8Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí

má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn

bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

9Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,

má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

10àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́

orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

11Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ

ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

12Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára

ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

13Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè

ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an

ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.

14Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò

ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

15Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà

ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

16Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba

bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.

17Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo

tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

18Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú

ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ

ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.

20Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,

tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,

ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.

2125.21,22: Ro 12.20.Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;

bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.

22Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí

Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

23Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá,

bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

24Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé

ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

25Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀

ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

26Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́

ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.

27Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,

bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

28Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀

ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

26

1Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè

ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.

2Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà

èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè

èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.

3Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.

4Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀

àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.

5Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀

àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

6Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá

ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.

7Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro

ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.

8Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa

ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.

9Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí

ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.

10Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.

1126.11: 2Pt 2.22.Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

12Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?

Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà

kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”

14Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.

15Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,

ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

16Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,

ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.

17Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú

ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.

18Bí i asínwín ti ń ju

ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni

19ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ

tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”

20Láìsí igi, iná yóò kú

láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

21Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,

bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.

22Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè

wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

23Ètè jíjóni, àti àyà búburú,

dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.

24Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀

ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

25Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́

nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.

26Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn

ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

27Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.

Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.

28Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,

ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.

27

1Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la

nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

2Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ,

àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.

3Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo

ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

4Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀

ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?

5Ìbániwí gbangba sàn

ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

6Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,

ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

7Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó

ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀

ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

9Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn

bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.

10Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,

má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ

ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.

11Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi

nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

12Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́

ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

13Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì

fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.

14Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀

a ó kà á sí bí èpè.

15Àyà tí ó máa ń jà dàbí

ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;

16dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun

tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

17Bí irin tí ń pọ́n irin mú

bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

18Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀

ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

19Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.

20Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí

bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.

21Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,

ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.

22Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,

fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́

ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.

23Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà

bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;

24nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí

adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

25Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé

26àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,

àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.

27Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́

láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ

àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

28

1Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e

ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.

2Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀,

ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.

3Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára

dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.

4Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú

ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.

5Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi

ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.

6Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù

ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.

7Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ

ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.

8Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù

ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.

9Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,

kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

10Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú

yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀

ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.

11Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀

ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.

12Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;

ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.

13Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.

14Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo

ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.

15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀

ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.

16Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú,

ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.

17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn

yóò máa joró rẹ̀ títí ikú

má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.

18Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,

ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.

19Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀

ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.

20Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an

ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.

21Ojúsàájú ṣíṣe kò dára,

síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.

22Ahun ń sáré àti là

kò sì funra pé òsì dúró de òun.

23Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn

ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.

24Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè

tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,”

irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.

25Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

26Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n

ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.

27Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun,

ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.

28Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora;

ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé,

àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.

29

1Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí

yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

2Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀

nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.

3Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀

ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.

4Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,

ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀

ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

6Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀

ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

7Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.

8Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,

ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

9Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n

aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin

wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú

ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12Bí olórí bá fetí sí irọ́,

gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,

Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́

ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.

15Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n

ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

16Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀

ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà

yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,

ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.

19A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́

bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.

20Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?

Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré

yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,

onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀

ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,

ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.

25Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,

ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:

ènìyàn búburú kórìíra olódodo.

30

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ.

1Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.

Sí Itieli àti sí Ukali.

2“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;

n kò ní òye ènìyàn.

3Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n

tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.

4Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?

Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?

Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?

Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?

Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?

Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

5“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;

òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.

6Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,

àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

7“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;

má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.

8Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;

má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,

ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.

9Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ

kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’

Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè

kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

10“Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,

kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.

11“Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn

tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn.

12Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn

síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;

13àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,

tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.

14Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà

àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ

láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé

àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.

15“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì.

‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké.

“Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,

mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:

16Ibojì, inú tí ó yàgàn,

ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,

àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’

17“Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,

tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá,

ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,

igún yóò mú un jẹ.

18“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,

mẹ́rin tí kò yé mi,

19ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú

ipa ejò lórí àpáta

ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun

àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

20“Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin

ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀

ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’

21“Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì

lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

22Ìránṣẹ́ tí ó di ọba

aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,

23obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ

ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24“Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé

síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.

25Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,

síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.

26Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá;

síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;

27àwọn eṣú kò ní ọba,

síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú,

síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

29“Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere,

ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:

30Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun

31Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́;

àti òbúkọ,

àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

32“Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,

tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,

da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!

33Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá,

tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,

bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”

31

Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli

1Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,

2“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!

Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.

3Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,

okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

4“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli,

kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì,

kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,

5kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí,

kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.

6Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé

wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.

7Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn

kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

8“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn

fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.

9Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè

jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

Ìkádìí: Aya oníwà rere

10Ta ni ó le rí aya oníwà rere?

Ó níye lórí ju iyùn lọ.

11Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀

kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi

ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀

Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;

ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.

15Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;

ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀

àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.

16Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;

nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

17Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára

apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.

18Ó rí i pé òwò òun pé

fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

19Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú

ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.

20O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà

ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

21Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀

nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

22Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;

ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

23A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú

níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.

24Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n

ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.

25Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ

ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

26A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n

ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

27Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀

kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.

28Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún

ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.

29“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá

ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”

30Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán

nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

31Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i

kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.