Ìwé Ẹkún Jeremiah

1

1Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,

nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!

Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

tí ó wà ní ipò opó,

ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú

ni ó padà di ẹrú.

2Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò

pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.

Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀

kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.

Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀

wọ́n ti di alátakò rẹ̀.

3Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,

Juda lọ sí àjò

Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.

Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́

ibi tí kò ti le sá àsálà.

4Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀,

nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn.

Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro,

àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,

àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú,

òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.

5Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,

nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,

Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́

nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,

ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

6Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé

kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.

Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín

tí kò rí ewé tútù jẹ;

nínú àárẹ̀ wọ́n sáré

níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.

7Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni

Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀

tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,

kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.

Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó

wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

8Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀

ó sì ti di aláìmọ́.

Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,

nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;

ó kérora fúnra rẹ̀,

ó sì lọ kúrò.

9Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀.

Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;

olùtùnú kò sì ṣí fún un.

“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,

nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”

10Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé

gbogbo ìní rẹ;

o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè

tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—

àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀

láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

11Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora

bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;

wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ

láti mú wọn wà láààyè.

“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,

nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”

12“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?

Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá.

Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà

tí a fi fún mi, ti

Olúwa mú wá fún mi

ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

13“Ó rán iná láti òkè

sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.

Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,

ó sì yí mi padà.

Ó ti pa mí lára

mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.

14“Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà;

ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.

Wọ́n ti yí ọrùn mi ká

Olúwa sì ti dín agbára mi kù.

Ó sì ti fi mí lé

àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.

15“Olúwa kọ

àwọn akọni mi sílẹ̀,

ó rán àwọn ológun lòdì sí mi

kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.

Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́

àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.

16“Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún

tí omijé sì ń dà lójú mi.

Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,

kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.

Àwọn ọmọ mi di aláìní

nítorí ọ̀tá ti borí.”

17Sioni na ọwọ́ jáde,

ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.

Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu

pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un

Jerusalẹmu ti di

ohun aláìmọ́ láàrín wọn.

18“Olóòtítọ́ ni Olúwa,

ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.

Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;

ẹ wò mí wò ìyà mi.

Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi

ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.

19“Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi

ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.

Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi

ṣègbé sínú ìlú

nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ

tí yóò mú wọn wà láààyè.

20Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!

Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,

ìdààmú dé bá ọkàn mi

nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.

Ní gbangba ni idà ń parun;

ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

21“Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,

ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.

Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;

wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.

Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,

kí wọ́n le dàbí tèmi.

22“Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;

jẹ wọ́n ní yà

bí o ṣe jẹ mí ní yà

nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Ìrora mi pọ̀

ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

2

1Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sioni

pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀!

Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀,

láti ọ̀run sí ayé;

kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀

ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

2Láìní àánú ni Olúwa gbé

ibùgbé Jakọbu mì;

nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó

ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀.

Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin

lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.

3Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké

gbogbo ìwo Israẹli.

Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò

nígbà tí àwọn ọ̀tá dé.

Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná

ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni.

4Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra.

Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun

ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná

sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.

5Olúwa dàbí ọ̀tá;

ó gbé Israẹli mì.

Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì

ó pa ibi gíga rẹ̀ run.

Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀

fún àwọn ọmọbìnrin Juda.

6Ó mú ìparun bá ibi mímọ́,

ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run.

Olúwa ti mú Sioni gbàgbé

àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn;

nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run

ọba àti olórí àlùfáà.

7Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀

ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.

Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́

àwọn odi ààfin rẹ̀;

wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa

gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.

8Olúwa pinnu láti fa

ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.

Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n,

kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.

Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀

wọ́n ṣòfò papọ̀.

9Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;

òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.

Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

kò sí òfin mọ́,

àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí

ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.

10Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni

jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;

wọ́n da eruku sí orí wọn

wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.

Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu

ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

11Ojú mi kọ̀ láti sọkún,

mo ń jẹ ìrora nínú mi,

mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀

nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,

nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú

ní òpópó ìlú.

12Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,

“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó

bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe

ní àwọn òpópónà ìlú,

bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò

láti ọwọ́ ìyá wọn.

13Kí ni mo le sọ fún ọ?

Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,

ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?

Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,

kí n lè tù ọ́ nínú,

ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?

Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.

Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14Ìran àwọn wòlíì rẹ

jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;

wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn

tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.

Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ

jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.

15Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ

pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;

wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn

sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:

“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè

ní àṣepé ẹwà,

ìdùnnú gbogbo ayé?”

16Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn

gbòòrò sí ọ;

wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke

wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.

Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;

tí a sì wá láti rí.”

17Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;

ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.

Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,

ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,

ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

18Ọkàn àwọn ènìyàn

kígbe jáde sí Olúwa.

Odi ọmọbìnrin Sioni,

jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò

ní ọ̀sán àti òru;

má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,

ojú rẹ fún ìsinmi.

19Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,

bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀

tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi

níwájú Olúwa.

Gbé ọwọ́ yín sókè sí i

nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀

tí ó ń kú lọ nítorí ebi

ní gbogbo oríta òpópó.

20“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó.

Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí.

Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,

àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?

Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì

ní ibi mímọ́ Olúwa?

21“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀

sínú eruku àwọn òpópó;

àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi

ti ṣègbé nípa idà.

Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ,

Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

22“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,

bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.

Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa

kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;

àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,

ni ọ̀tá mi parun.”

3

1Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú

pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.

2Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn

nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.

3Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi

síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.

4Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó

ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.

5Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká

pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.

6Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,

bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

7Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;

ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.

8Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,

ó kọ àdúrà mi.

9Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;

ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

10Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀,

bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.

11Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀

ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.

12Ó fa ọfà rẹ̀ yọ

ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.

13Ó fa ọkàn mí ya

pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

14Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi;

wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

15Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò

àti ìdààmú bí omi.

16Ó ti fi òkúta kán eyín mi;

ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

17Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;

mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

18Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ

àti ìrètí mi nínú Olúwa.”

19Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,

ìkorò àti ìbànújẹ́.

20Mo ṣèrántí wọn,

ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

21Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

àti nítorí náà ní mo nírètí.

22Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

23Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

títóbi ni òdodo rẹ̀.

24Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;

nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

25Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,

sí àwọn tí ó ń wá a.

26Ó dára kí a ní sùúrù

fún ìgbàlà Olúwa.

27Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà

nígbà tí ó wà ní èwe.

28Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,

nítorí Olúwa ti fi fún un.

29Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku—

ìrètí sì lè wà.

30Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,

sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31Ènìyàn kò di ìtanù

lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

32Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,

nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

33Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá

tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

34Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀

gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

35Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀

níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,

36láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà,

ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

37Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀

tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.

38Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ

ni rere àti búburú tí ń wá?

39Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn

nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,

kí a sì tọ Olúwa lọ.

41Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè

sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,

42“Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀

ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

43“Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;

ìwọ ń parun láìsí àánú.

44Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ

pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

45Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn

láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

46“Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn

gbòòrò sí wa.

47Àwa ti jìyà àti ìparun,

nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”

48Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò

nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49Ojú mi kò dá fún omijé,

láì sinmi,

50títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀

láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

51Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi

nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

52Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí

dẹ mí bí ẹyẹ.

53Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò

wọ́n sì ju òkúta lù mí.

54Orí mi kún fún omi,

mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,

láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

56Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ

sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”

57O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,

o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

58Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,

o ra ẹ̀mí mi padà.

59O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi.

Gba ẹjọ́ mi ró!

60Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,

gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

61Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn

àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,

62ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ

sí mi ní gbogbo ọjọ́.

63Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,

wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.

64Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn

fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.

65Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,

kí o sì fi wọ́n ré.

66Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,

lábẹ́ ọ̀run Olúwa.

4

1Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,

wúrà dídára di àìdán!

Òkúta ibi mímọ́ wá túká

sí oríta gbogbo òpópó.

2Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,

tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe

wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán

iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

3Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn

fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,

ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn

bí ògòǹgò ní aginjù.

4Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́

lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;

àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ,

ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.

5Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára

di òtòṣì ní òpópó.

Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀

ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.

6Ìjìyà àwọn ènìyàn mi

tóbi ju ti Sodomu lọ,

tí a sí ní ipò ní òjijì

láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

7Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì,

wọ́n sì funfun ju wàrà lọ

wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,

ìrísí wọn dàbí safire.

8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú;

wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.

Ara wọn hun mọ́ egungun;

ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

9Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn

ju àwọn tí ìyàn pa;

tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò

fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

10Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú

ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ

tí ó di oúnjẹ fún wọn

nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

11Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;

ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.

Ó da iná ní Sioni

tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,

tàbí àwọn ènìyàn ayé,

wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ

odi ìlú Jerusalẹmu.

13Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì

àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,

tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo

sílẹ̀ láàrín rẹ̀.

14Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó

bí ọkùnrin tí ó fọ́jú.

Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n

tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

15“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.

“Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”

Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,

“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

16Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀;

kò sí bojútó wọn mọ́.

Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,

àti àánú fún àwọn àgbàgbà.

17Síwájú sí i, ojú wa kùnà

fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;

láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò

fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

18Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,

àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.

Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye

nítorí òpin wa ti dé.

19Àwọn tí ń lé wa yára

ju idì ojú ọ̀run lọ;

wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè

wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.

20Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa,

ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.

Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀

ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

21Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu,

ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi.

Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;

ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.

22Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin;

kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́.

Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà

yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.

5

1Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;

wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

2Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,

ilé wa ti di ti àjèjì.

3Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,

àwọn ìyá wa ti di opó.

4A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;

igi wa di títà fún wa.

5Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;

àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria

láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

7Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,

àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,

kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa

nítorí idà tí ó wà ní aginjù.

10Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,

ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

11Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,

àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.

12Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;

kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.

13Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;

àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

14Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;

àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.

15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;

ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

16Adé ti ṣí kúrò ní orí wa

ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

17Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,

nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

18Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro

lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

19Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;

ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

20Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?

Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

21Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;

mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,

22àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá

tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.