Ìwé Wòlíì Jeremiah

1

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. 2Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, 3àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Ìpè Jeremiah

4Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,

51.5: Isa 49.1; Ga 1.15.“Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,

kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.

Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”

6Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.”

7Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” 81.8: Isa 43.5; Ap 18.9-10.Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.

9Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ. 101.10: If 10.11.Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.

11Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé, “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?”

Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14Olúwa sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

“Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró

ní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu.

Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn

àti sí gbogbo àwọn ìlú Juda.

16Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi

nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,

nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn

àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

2

Israẹli kọ Ọlọ́run sílẹ̀

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: 2“Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé:

“Báyìí ni Olúwa wí,

“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,

ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ

àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,

nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.

3Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa,

àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,

gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,

ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

4Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu

àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.

5Báyìí ni Olúwa wí:

“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi,

tí wọ́n fi jìnnà sí mi?

Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,

àwọn fúnra wọn sì di asán.

6Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,

tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,

tí ó mú wa la aginjù já,

tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,

ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,

ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’

7Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá

láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,

ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.

8Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,

‘Níbo ni Olúwa wà?’

Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,

àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.

Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,

wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.

9“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”

ni Olúwa wí.

“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ.

10Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,

ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi;

kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?

11Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà?

(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.)

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀

Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.

12Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì

kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”

ni Olúwa wí.

13“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,

wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,

Èmi orísun omi ìyè,

wọ́n sì ti ṣe àmù,

àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.

14Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí?

Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun?

15Àwọn kìnnìún ké ramúramù;

wọ́n sì ń bú mọ́ wọn.

Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò;

ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.

16Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi

wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.

17Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín

nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀

nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?

18Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti

láti lọ mu omi ní Ṣihori?

Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria

láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?

19Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín

ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí

mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti

ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ

nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,

ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”

ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

20“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù,

ìwọ sì já ìdè rẹ;

ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’

Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni

àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀

ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.

21Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀,

gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá.

Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi

di àjàrà búburú àti aláìmọ́?

22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà

tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ

síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”

ni Olúwa Olódùmarè wí.

23“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́,

Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?

Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;

wo ohun tí o ṣe.

Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ

tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún.

24Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù

tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,

ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?

Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,

nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.

25Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,

àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.

Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!

Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,

àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’

26“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,

bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—

àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,

àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.

27Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’

àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’

wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,

wọn kò kọ ojú sí mi

síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,

wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’

28Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà?

Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín

nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro!

Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀,

gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.

29“Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?

Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”

ni Olúwa wí.

30“Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,

wọn kò sì gba ìbáwí.

Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,

gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.

31“Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa:

“Mo ha ti di aginjù sí Israẹli

tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri?

Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri;

àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’

32Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,

tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀?

Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi

ní ọjọ́ àìníye.

33Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́!

Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ.

34Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá

ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé.

Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí

35ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀;

kò sì bínú sí mi.’

Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ

nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’

36Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri

láti yí ọ̀nà rẹ padà?

Ejibiti yóò dójútì ọ́

gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria.

37Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀

pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ,

nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀,

kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.

3

1“Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn,

ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá?

Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí?

Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́,

ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?”

ni Olúwa wí.

2“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì,

kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́?

Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,

bí i ará Arabia kan nínú aginjù,

ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́

pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.

3Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,

kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò.

Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,

ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.

4Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé,

‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

5Ìwọ yóò ha máa bínú títí?

Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’

Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀

ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”

Israẹli aláìṣòótọ́

6Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀. 7Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i. 8Mo fún Israẹli aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Síbẹ̀ mo rí pé Juda tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè. 9Nítorí ìwà èérí Israẹli kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi. 10Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni Olúwa wí.

11Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ. 12Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:

“ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.

‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́,

nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.

Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé.

13Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,

ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,

ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì

lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,

ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”

ni Olúwa wí.

14“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni. 15Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀. 16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́. 17Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́. 18Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

19“Èmi fúnra mi sọ wí pé,

“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó,

kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin

kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’

Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’

o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.

20Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,”

ni Olúwa wí.

21A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,

ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli,

nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,

wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

22“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,

Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.”

“Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ

nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.

23Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè

kéékèèké àti àwọn òkè gíga,

nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run

wa ni ìgbàlà Israẹli wà.

24Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti

jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,

ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,

ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

25Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,

kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.

A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa,

àwa àti àwọn baba wa,

láti ìgbà èwe wa títí di òní

a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

4

1“Tí ìwọ yóò bá yí padà, ìwọ Israẹli, padà tọ̀ mí wá,”

ni Olúwa wí.

“Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi,

ìwọ kí ó sì rìn kiri.

2Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra.

Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè,

nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ,

àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”

3Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu:

“Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,

kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.

4Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa,

kọ ọkàn rẹ ní ilà,

ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu,

bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,

nítorí ibi tí o ti ṣe

kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

Àjálù láti ilẹ̀ gúúsù

5“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé:

‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’

Kí o sì kígbe:

‘Kó ara jọ pọ̀!

Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’

6Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn,

sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.

Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,

àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

7Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,

apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde.

Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀

láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.

Ìlú rẹ yóò di ahoro

láìsí olùgbé.

8Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀

káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún,

nítorí ìbínú ńlá Olúwa

kò tí ì kúrò lórí wa.

9“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,

“Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,

àwọn àlùfáà yóò wárìrì,

àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”

10Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”

11Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. 12Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”

13Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu

kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle

ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ.

Ègbé ni fún wa àwa parun.

14Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè.

Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?

15Ohùn kan sì ń kéde ní Dani

o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.

16“Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè,

kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé:

‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá

wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda.

17Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,

nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”

ni Olúwa wí.

18“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ

ló fa èyí bá ọ

ìjìyà rẹ sì nìyìí.

Báwo ló ti ṣe korò tó!

Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19Háà! Ìrora mi, ìrora mi!

Mo yí nínú ìrora.

Háà, ìrora ọkàn mi!

Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,

n kò le è dákẹ́.

Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,

mo sì ti gbọ́ igbe ogun.

20Ìparun ń gorí ìparun;

gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun

lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi,

tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

21Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun

tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

22“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi;

wọn kò mọ̀ mí.

Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ;

wọ́n sì jẹ́ aláìlóye.

Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe;

wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

23Mo bojú wo ayé,

ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo

àti ní ọ̀run,

ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.

24Mo wo àwọn òkè ńlá,

wọ́n wárìrì;

gbogbo òkè kéékèèké mì jẹ̀jẹ̀.

25Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan;

gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.

26Mo bojú wò, ilẹ̀ eléso, ó sì di aṣálẹ̀

gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun

níwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀.

27Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro,

síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá.

28Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún

àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn

nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀

mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”

29Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà

gbogbo ìlú yóò sálọ.

Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;

ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.

Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;

kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.

30Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán?

Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo

kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.

Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ;

wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

31Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí,

tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ

ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀.

Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé,

“Kíyèsi i mo gbé,

nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

5

Kò sí ọ̀kan tí o jẹ́ olóòtítọ́

1“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu,

wò yíká, kí o sì mọ̀,

kí o sì wá kiri.

Bí o bá le è rí ẹnìkan,

tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo,

n ó dáríjì ìlú yìí.

2Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’

síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

3Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́?

Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n;

ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.

Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,

wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

4Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí;

wọn jẹ́ aṣiwèrè,

nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,

àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

5Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,

n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;

ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa

àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,

wọ́n sì ti já ìdè.

6Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,

ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run,

ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín

ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,

nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,

ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

7“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?

Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀

àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.

Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn,

síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà

wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.

8Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,

tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.

9Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi

lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

10“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,

ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.

Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,

nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

11Ilé Israẹli àti ilé Juda

ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”

ni Olúwa wí.

12Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;

wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!

Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;

àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.

13Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,

ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.

Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”

14Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí:

“Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí;

Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná,

àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.

15Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí,

“Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín

Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì

àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,

tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.

16Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí

gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

17Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,

àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,

wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,

wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.

Pẹ̀lú idà ni wọn ó run

ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.

18“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’

20“Kéde èyí fún ilé Jakọbu,

kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.

215.21: Isa 6.9-10; Mt 13.10-15; Mk 8.17-18.Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,

tí ó lójú ti kò fi ríran

tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.

22Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?”

ni Olúwa wí.

“Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?

Mo fi yanrìn pààlà òkun,

èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.

Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;

wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

23Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,

wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.

24Wọn kò sọ fún ara wọn pé,

‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,

tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’

25Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,

ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà

tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,

àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.

27Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,

ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn;

wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

28wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.

Ìwà búburú wọn kò sì lópin;

wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.

Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

29Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi

lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

30“Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara

ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.

31Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,

àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,

àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí,

kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

6

Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbèkùn

1“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!

Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.

Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!

Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu!

Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,

àní ìparun tí ó lágbára.

2Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,

tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.

3Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.

Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,

olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

4“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!

Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!

Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,

ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́

kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

6Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀

kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.

Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,

nítorí pé ó kún fún ìninilára.

7Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,

náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.

Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;

nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.

8Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀,

kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,

kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,

tí kò ní ní olùgbé.”

9Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli

ní tónítóní bí àjàrà;

na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i

gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”

10Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn?

Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi?

Etí wọn ti di,

nítorí náà wọn kò lè gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,

wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.

11Èmi kún fún ìbínú Olúwa,

èmi kò sì le è pa á mọ́ra.

“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro,

àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀,

àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀,

àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.

12Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,

oko wọn àti àwọn aya wọn,

nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi

sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”

ni Olúwa wí.

13“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju,

gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,

àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀

sì kún fún ẹ̀tàn.

14Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn

mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.

Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’

nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.

15Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí?

Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́,

wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú.

Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú,

a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”

ni Olúwa wí.

16Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,

ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́,

ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,

ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’

17Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,

mo sì wí pé:

‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’

ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’

18Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí,

ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19Gbọ́, ìwọ ayé!

Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,

èso ìrò inú wọn,

nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,

wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.

20Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,

tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?

Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,

ọrẹ yín kò sì wù mí.”

21Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,

àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”

22Báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,

a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde

láti òpin ayé wá.

23Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,

wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú.

Wọ́n ń hó bí omi Òkun,

bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;

wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun,

ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”

24Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,

ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa

bí obìnrin tí ń rọbí.

25Má ṣe jáde lọ sí orí pápá

tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà,

nítorí ọ̀tá náà ní idà,

ìpayà sì wà níbi gbogbo.

26Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,

kí ẹ sì sùn nínú eérú,

ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún

gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo

nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.

27“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́

irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù,

kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,

kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.

28Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.

Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.

Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,

wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

29Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,

kí ó lè yọ́ òjé,

ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;

a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.

30A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,

nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”

7

Ẹ̀sìn àìṣòótọ́ kò níláárí

1Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa. 2“Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí:

“ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa. 3Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí. 4Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili Olúwa ilé tẹmpili Olúwa, ilé tẹmpili Olúwa!” 5Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti iṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́. 6Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín. 7Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé. 8Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.

9“ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ? 10Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? 117.11: Mt 21.13; Mk 11.17; Lk 19.46.Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.

12“ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. 13Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn. 14Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín. 15Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’

16“Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. 17Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 18Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. 19Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?

20“ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.”

21“ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín. 22Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. 23Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé; gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. 24Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. 25Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. 26Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’

27“Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. 28Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn.

29“ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.

Àfonífojì ìparun

30“ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. 31Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. 32Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́. 33Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 347.34: If 18.23.Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

8

1“ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. 2A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’

Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà

4“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí?

Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí?

5Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀?

Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?

Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn;

wọ́n kọ̀ láti yípadà.

6Mo ti fetísílẹ̀ dáradára,

wọn kò sọ ohun tí ó tọ́.

Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,

kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?”

Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀

gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.

7Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run

mọ ìgbà tirẹ̀,

àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé

mọ àkókò ìṣípò padà wọn.

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ

ohun tí Olúwa wọn fẹ́.

8“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,

nítorí a ní òfin Olúwa,”

nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé

ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.

9Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n,

a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.

Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,

irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?

10Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn

àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn.

Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù,

gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún;

àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà

pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.

11Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi

gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀.

“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,

nígbà tí kò sí àlàáfíà.

12Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn?

Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá;

wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú.

Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,

a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,

ni Olúwa wí.

13“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò,

ni Olúwa wí.

Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà.

Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi,

ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.

Ohun tí mo ti fi fún wọn

ni à ó gbà kúrò.’ ”

14“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?

A kó ara wa jọ!

Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi

kí a sì ṣègbé síbẹ̀.

Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé.

Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu,

nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.

15Àwa ń retí àlàáfíà

kò sí ìre kan,

tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá

bí kò ṣe ìpayà nìkan.

16Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀

là ń gbọ́ láti Dani,

yíyan àwọn akọ ẹṣin

mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì.

Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run,

gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,

ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.

17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,

paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn,

yóò sì bù yín jẹ,”

ni Olúwa wí.

18Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,

rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi

láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:

Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?

Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”

“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn,

pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”

20“Ìkórè ti rékọjá,

ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,

síbẹ̀ a kò gbà wá là.”

21Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,

èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.

22Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?

Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?

Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn

fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?

9

1Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi

kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!

Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru

nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.

2Háà, èmi ìbá ní ni aginjù

ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,

kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀

kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:

nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà

àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.

3Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀

bí ọfà láti fi pa irọ́;

kì í ṣe nípa òtítọ́

ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.

Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;

wọn kò sì náání mi,

Olúwa wí.

4“Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;

má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.

Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,

oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

5Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni

tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn

láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn

di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

6Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn;

wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,”

ni Olúwa wí.

7Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Wò ó, èmi dán wọn wo;

nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe?

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?

8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;

ó ń sọ ẹ̀tàn.

Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,

ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”

ni Olúwa wí.

“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara

mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”

10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè

àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.

Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀.

A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn.

Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ,

bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì

àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.

Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro

tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”

12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”

17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:

“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;

sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

18Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,

kí wọn wá pohùnréré ẹkún

lé wa lórí títí ojú wa yóò

fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.

19A gbọ́ igbe ìpohùnréré

ẹkún ní Sioni:

‘Àwa ti ṣègbé tó!

A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,

nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”

20Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa;

ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún,

kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.

21Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé

ó sì ti wọ odi alágbára wa

ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò

àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.

22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú

bí ààtàn ní oko gbangba

àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè

láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”

23Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,

tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,

tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

249.24: 1Kọ 1.31; 2Kọ 10.17.Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:

òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,

Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,

ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,

nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”

Olúwa wí.

25“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan. 26Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

10

Ọlọ́run àti àwọn òrìṣà

1Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. 2Báyìí ni Olúwa wí:

“Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí,

kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín,

nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.

3Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,

wọ́n gé igi láti inú igbó,

oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.

4Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó

kí ó má ba à ṣubú.

5Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,

òrìṣà wọn kò le è fọhùn.

Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé

wọn nítorí pé wọn kò lè rìn.

Má ṣe bẹ̀rù wọn;

wọn kò le è ṣe ibi kankan

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

6Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;

o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.

7Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?

Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?

Nítorí tìrẹ ni.

Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè

àti gbogbo ìjọba wọn,

kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

8Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,

wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí.

9Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi,

àti wúrà láti Upasi.

Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n

kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,

èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.

10Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,

òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.

Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;

orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.

11“Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,

ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,

ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.

13Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo;

ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé.

Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,

ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,

ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,

nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,

kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.

15Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;

nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé.

16Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,

nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo

àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀.

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Ìparun tí n bọ̀ wá

17Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀

ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.

18Nítorí èyí ni Olúwa wí:

“Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn

àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde.

Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn,

kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”

19Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!

Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,

bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,

“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”

20Àgọ́ mi bàjẹ́,

gbogbo okùn rẹ̀ sì já.

Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́,

kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,

tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi.

21Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,

wọn kò sì wá Olúwa:

nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere

àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.

22Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,

àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!

Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,

àti ihò ọ̀wàwà.

Àdúrà Jeremiah

23Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,

kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.

24Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan

kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,

kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.

2510.25: 1Tẹ 4.5; If 16.1.Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè

tí kò mọ̀ ọ́n,

sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ.

Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,

wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá,

wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.

11

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá: 2“Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Juda, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jerusalẹmu. 3Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́. 4Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi, Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 5Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.”

Mo sì dáhùn wí pé, “Àmín, Olúwa.”

6Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda àti ní gbogbo òpópónà ìgboro Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì se wọn. 7Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.” 8Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ”

9Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrín àwọn ará Juda àti àwọn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. 10Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí wọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti ba májẹ̀mú tí mo dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn jẹ́. 11Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn. 12Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé. 13Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’

14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.

15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,

bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?

Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?

Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,

nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”

16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi

pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle

ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún

tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.

17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

Ọ̀tẹ̀ sí Jerusalẹmu

18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí. 19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; n kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé:

“Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀;

jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè,

kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,

tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn,

jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn;

nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Anatoti tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’ 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 23Kò ní ṣẹ́kù ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Anatoti ní ọdún ìbẹ̀wò wọn.’ ”

12

Ọ̀rọ̀ Jeremiah

1Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà,

nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.

Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.

Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé?

Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?

2Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,

wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.

Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,

o jìnnà sí ọkàn wọn.

3Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,

o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.

Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.

Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.

4Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà,

tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ?

Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀.

Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé,

pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé,

“Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”

Ìdáhùn Ọlọ́run

5Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré,

tí àárẹ̀ sì mú ọ,

báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje?

Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà,

bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé,

kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani?

6Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn

ìdílé

ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ,

wọ́n ti hó lé ọ lórí.

Má ṣe gbà wọ́n gbọ́

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

7Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,

èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀.

Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́

lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8Ogún mi ti rí sí mi

bí i kìnnìún nínú igbó.

Ó ń bú ramúramù mọ́ mi;

nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

9Ogún mi kò ha ti rí sí mi

bí ẹyẹ kannakánná

tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?

Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ,

ẹ mú wọn wá jẹ.

10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,

tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;

wọ́n ó sọ oko dídára mi di

ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

11A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀

tí kò wúlò níwájú mi,

gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro

nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.

12Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀

ni àwọn apanirun ti gorí,

nítorí idà Olúwa yóò pa

láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà;

kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.

13Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,

wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.

Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,

nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

14Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn. 15Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù. 16Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi. 17Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.

13

O wé aṣọ funfun

1Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.” 2Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

3Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì, 4“Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.” 5Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

6Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.” 7Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

8Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 9“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu. 10Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun. 11Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

Ọtí Wáìnì

12“Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’ 13Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu. 14Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”

Ìkìlọ̀ oko ẹrú

15Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,

ẹ má ṣe gbéraga,

nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

16Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,

kí ó tó mú òkùnkùn wá,

àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé

lórí òkè tí ó ṣókùnkùn.

Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,

òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri.

17Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,

Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀

nítorí ìgbéraga yín.

Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,

tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde,

nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18Sọ fún ọba àti ayaba pé,

“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,

ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,

adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,

kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.

Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,

gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

20Gbé ojú rẹ sókè,

kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.

Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;

àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ

àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.

Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ

bí aboyún tó ń rọbí?

22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè,

“Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀

ni aṣọ rẹ fi fàya

tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

23Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?

Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?

Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀

náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

24“N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò

tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.

25Èyí ni ìpín tìrẹ;

tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”

ni Olúwa wí,

“Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi

o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.

26N ó sí aṣọ lójú rẹ,

kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta—

27ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,

àìlójútì panṣágà rẹ!

Mo ti rí ìwà ìríra rẹ,

lórí òkè àti ní pápá.

Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu!

Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

14

Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

2“Juda káàánú,

àwọn ìlú rẹ̀ kérora

wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,

igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.

3Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,

wọ́n lọ sí ìdí àmù

ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.

Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;

ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,

wọ́n sì bo orí wọn.

4Ilẹ̀ náà sán

nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;

ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,

wọ́n sì bo orí wọn.

5Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá

fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,

torí pé kò sí koríko.

6Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo

wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò

ojú wọn kò ríran

nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

7Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,

wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.

Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,

a ti ṣẹ̀ sí ọ.

8Ìrètí Israẹli;

ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,

èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà

bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

9Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,

bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?

Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,

orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;

má ṣe fi wá sílẹ̀.

10Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:

“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;

wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.

Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;

yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,

yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

11Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 1214.12: If 6.8.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

13Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

14Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

17“Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:

“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé

ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;

nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,

ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá

pẹ̀lú lílù bolẹ̀.

18Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,

Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.

Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,

èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.

Wòlíì àti Àlùfáà

ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?

Ṣé o ti ṣá Sioni tì?

Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú

tí a kò fi le wò wá sàn?

A ń retí àlàáfíà

ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,

ní àsìkò ìwòsàn

ìpayà là ń rí.

20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa

àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;

lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

21Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;

má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.

Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá

kí o má ṣe dà á.

22Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?

Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí?

Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.

Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,

nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

15

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! 215.2: If 13.10.Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí:

“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;

àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;

àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;

àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’

3“Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun. 4N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

5“Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu?

Ta ni yóò dárò rẹ?

Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?

6O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí,

“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.

Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run,

Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.

7Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ,

Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà.

Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun

bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn

kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.

8Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju

yanrìn Òkun lọ.

Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun

kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.

Lójijì ni èmi yóò mú

ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.

9Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú,

yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn.

Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan,

yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù.

Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú

àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”

ni Olúwa wí.

10Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi,

ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà!

Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni,

síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

11Olúwa sọ pé,

“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó;

dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ

nígbà ibi àti ìpọ́njú.

12“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin

irin láti àríwá tàbí idẹ?

13“Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ

ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba

nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ

jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.

14Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ

ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú

mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”

15Ó yé ọ, ìwọ Olúwa;

rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi.

Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi.

Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ;

nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.

16Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n,

àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi,

nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí,

Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.

17Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn,

n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;

mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi,

ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.

18Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,

tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?

Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,

gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

19Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí,

“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá

kí o lè máa sìn mí;

tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára,

ìwọ yóò di agbẹnusọ mi.

Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;

ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.

20Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára,

sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí;

wọn ó bá ọ jà

ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ,

nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ

láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,”

ni Olúwa wí.

21“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn,

Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

16

Ọjọ́ àjálù

1Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.” 3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn. 4“Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

5Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí. 6“Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn. 7Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.

8“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu. 9Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.

10“Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’ 11Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́. 12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Wò ó bí gbogbo yín ṣe ń rìn, olúkúlùkù yín nínú agídí ọkàn búburú rẹ̀, dípò kí ẹ fi gbọ́ tèmi. 13Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí baba yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn ọlọ́run kéékèèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’

14“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.

16“Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”

19Olúwa, alágbára àti okun mi,

ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú,

àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti

òpin ayé wí pé,

“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,

ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.

20Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run

fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,

ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”

21“Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn

ní àkókò yìí,

Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi.

Nígbà náà ni wọn ó mọ

pé orúkọ mi

Olúwa.

17

1“Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,

èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,

sórí wàláà oókan àyà wọn,

àti sórí ìwo pẹpẹ yín.

2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ

àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ

àti àwọn òkè gíga.

3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀

àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ

pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó

pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.

4Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin

yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.

Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú

ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,

nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,

èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

5Báyìí ni Olúwa wí:

“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,

tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,

àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,

kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,

yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,

ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

717.7-8: Sm 1.1-3.“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin

náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi

Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò

tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò

kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,

gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù

kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá

bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

9Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,

ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.

Ta ni èyí lè yé?

1017.10: Sm 62.12; If 2.23; 22.12.“Èmi Olúwa ń wo ọkàn

àti èrò inú ọmọ ènìyàn,

láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,

àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé

ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo.

Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀,

àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀

ní ibi ilé mímọ́ wa.

13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;

gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.

Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ

ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,

nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,

orísun omi ìyè sílẹ̀.

14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,

gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,

nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15Wọ́n sọ fún mi wí pé:

“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?

Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”

Ni Olúwa wí.

16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,

ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.

Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,

ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.

18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,

ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,

jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.

Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,

fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́

19Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.” 23Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa. 27Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

18

Ní ilé amọ̀kòkò

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: 2“Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 3Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. 4Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 618.6: Ro 9.21.“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun, 8tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.

11“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,

ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?

Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.

14Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni

yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?

Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,

tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?

15Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,

wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,

tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,

àti ọ̀nà wọn àtijọ́.

Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,

àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.

16Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di

nǹkan ẹ̀gàn títí láé,

gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,

wọn yóò sì mi orí wọn.

17Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,

Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.

Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn

ní ọjọ́ àjálù wọn.”

18Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”

19Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa,

gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

20Ṣe kí a fi rere san búburú?

Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi.

Rántí pé mo dúró níwájú rẹ,

mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn,

láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

21Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn

jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà

jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó

jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn

kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin

wọn lójú ogun.

22Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn

nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun

kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́

kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi.

23Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ

gbogbo ète wọn láti pa mí,

má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n

bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.

Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.

19

1Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì. 2Kí o sì lọ sí àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ. 3Kí o sì wí pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya. 4Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí. 5Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi. 6Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.

7“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. 8Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. 9Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

10“Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 1319.13: Ap 7.42.Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

14Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, 15“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”

20

Jeremiah àti Paṣuri

1Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. 2Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. 320.3,10: Jr 6.25; 46.5; 49.29; Sm 31.13.Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. 4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. 5Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. 6Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

Ìráhùn Jeremiah

7Olúwa, o tàn mí jẹ́,

o sì ṣẹ́gun.

Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,

gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.

8Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta

èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.

Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù

àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.

9Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ

tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi

nínú egungun mi,

agara dá mi ní inú mi

nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.

10Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,

ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo.

Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!

Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró

kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,

bóyá yóò jẹ́ di títàn,

nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,

àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.

Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,

wọn kì yóò sì borí.

Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.

Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

12Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò

tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,

jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,

nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13Kọrin sí Olúwa!

Fi ìyìn fún Olúwa!

Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní

lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!

Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.

15Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,

tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,

“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”

16Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú

Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú

Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,

ariwo ogun ní ọ̀sán.

17Nítorí kò pa mí nínú,

kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,

kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.

18Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,

láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀

àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?

21

Ọlọ́run kọ ìbéèrè Sedekiah sílẹ̀

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá nígbà tí ọba Sedekiah rán Paṣuri ọmọ Malkiah àti àlùfáà Sefaniah ọmọ Maaseiah sí i; wọ́n wí pé: 2“Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadnessari ọba Babeli ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”

3Ṣùgbọ́n Jeremiah dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekiah, 4‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí. 5Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle. 6Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú. 7Olúwa sọ pé lẹ́yìn èyí, èmi yóò fi Sedekiah ọba Juda, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn, àti àwọn tí ó kù ní ìlú yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn àti lọ́wọ́ idà, àti lọ́wọ́ ìyàn; èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé ọwọ́ àwọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn, òun yóò sì fi ojú idà pa wọ́n, kì yóò sì dá wọn sí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ní ìyọ́nú tàbí ṣàánú wọn.’

8“Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín. 9Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. 10Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’

11“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:

“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;

yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára

ẹni tí a ti jà lólè

bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.

Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó

láìsí ẹni tí yóò pa á.

13Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu,

ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì

lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí.

Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá?

Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?”

14Èmi yóò jẹ ọ ní ìyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀

ni Olúwa wí.

Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀;

yóò si jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”

22

Ìdájọ́ fún àwọn ọba búburú

1Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀: 2‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí. 3Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí. 4Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 5Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

6Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,

gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,

dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,

àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

7Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,

olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,

wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,

wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

8“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’ 9Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”

10Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,

ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú

nítorí kì yóò padà wá mọ́

tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.

11Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́. 12Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”

13“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo,

àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́

tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán

láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.

14Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi

àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,

ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’

A ó sì fi igi kedari bò ó,

a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.

15“Ìwọ ó ha jẹ ọba

kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari?

Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?

Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo,

nítorí náà ó dára fún un.

16Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní,

ohun gbogbo sì dára fún un.

Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?”

ni Olúwa wí.

17“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ

wà lára èrè àìṣòótọ́

láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀

ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

18Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:

wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’

Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:

wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’

19A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè

Jerusalẹmu.”

20“Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta,

kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani,

kí o kígbe sókè láti Abarimu,

nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.

21Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,

ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’

Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,

ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

22Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,

gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn,

nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́

nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.

23Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’

tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari,

ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,

ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!

24“Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀. 25Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli. 26Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí. 27Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”

28Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,

ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?

Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè

sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.

29Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,

gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

30Báyìí ni Olúwa wí:

“Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,

ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀;

nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere,

èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi

tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”

23

Ẹ̀ka òtítọ́

1“Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí. 2Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí. 3“Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. 4Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.

523.5: Jr 33.15; Isa 4.2; Sk 3.8; 6.12.“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,

“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,

ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n

tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.

6Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là,

Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu.

Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é:

Olúwa Òdodo wa.

7Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’ 8Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”

Àwọn wòlíì èké

9Nípa ti àwọn wòlíì èké.

Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,

gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.

Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,

bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;

nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn;

nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ,

àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ.

Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú,

wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.

11“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run;

kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,”

ni Olúwa wí.

12“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́,

a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn;

níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú.

Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn,

ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,”

ni Olúwa wí.

13“Láàrín àwọn wòlíì Samaria,

Èmi rí ohun tí ń lé ni sá.

Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali

wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.

14Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu,

èmi ti rí ohun búburú.

Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké.

Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára,

tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.

Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi,

àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”

15Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì:

“Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò,

wọn yóò mu omi májèlé

nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu

ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”

16Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín.

Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán.

Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn,

kì í ṣe láti ẹnu Olúwa.

17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé,

Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’

Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé,

‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’

18Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró

nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i

tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?

Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?

19Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde

pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí

orí àwọn olùṣe búburú.

20Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀

títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ,

ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.

21Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí

síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn.

Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀,

síbẹ̀ wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22Ṣùgbọ́n ì bà ṣe pé wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi,

wọn ìbá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi.

Wọn ìbá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi fun àwọn ènìyàn

wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà

àti ìṣe búburú wọn.

23“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?”

ni Olúwa wí,

“kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn.

24Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan,

kí èmi má ba a rí?”

ni Olúwa wí.

“Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?”

ni Olúwa wí.

25“Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’ 26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn? 27Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sí sin òrìṣà Baali. 28Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí. 29“Ọ̀rọ̀ mi kò ha a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?

30“Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” Olúwa wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn. 31Bẹ́ẹ̀,” ni Olúwa wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń sọ wí pé, ‘Olúwa wí.’ 32Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni Olúwa wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni Olúwa wí.

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ èké àti àwọn wòlíì èké

33“Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni Olúwa wí.’ 34Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀. 35Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa?’ Tàbí ‘Kí ni ohun tí Olúwa sọ?’ 36Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ Olúwa’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run wa padà. 37Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa sí ọ́?’ Tàbí ‘Kí ni ohun tí Olúwa bá ọ sọ?’ 38Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ èyí ni ohun tí Olúwa sọ, Ẹ̀yin ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe lò ó mọ́, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ 39Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn ìlú tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín. 40Èmi yóò sì mú ìtìjú ayérayé wá sí orí yín, ìtìjú tí kò ní ní ìgbàgbé.”

24

Agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì

1Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa. 2Agbọ̀n kan ni èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ.

3Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremiah?”

Mo dáhùn pe, “Èso ọ̀pọ̀tọ́.” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dáradára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

4Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 5“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjèjì láti Juda sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea. 6Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere, Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu. 7Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, “Èmi ni Olúwa.” Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

8“ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti. 9Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí. 10Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’ ”

25

Àádọ́rin ọdún nínú oko ẹrú

1Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli. 2Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu. 3Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.

4Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀. 5Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Olúwa fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé. 6Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”

7“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”

8Nítorí náà, Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, 9Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé. 1025.10: Jr 7.34; 16.9; If 18.23.Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. 11Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.

12“Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé. 13Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. 14Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Ago ìbínú Ọlọ́run

1525.15: Jr 51.7; If 14.8,10; 16.19; 17.4; 18.3.Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún. 16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.” 17Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.

18Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.

19Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀. 20Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀;

gbogbo àwọn ọba Usi,

gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.

21Edomu, Moabu àti Ammoni;

22gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni;

gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.

23Dedani, Tema, Busi àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jíjìn réré.

24Gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn ọba àwọn àjèjì ènìyàn tí ń gbé inú aginjù.

25Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.

26Àti gbogbo àwọn ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jíjìn, ẹnìkínní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé.

Àti gbogbo wọn, ọba Ṣeṣaki náà yóò sì mu.

27“Nígbà náà, sọ fún wọn, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí. Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín. 28Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún! 29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

30“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:

“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,

yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.

Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.

31Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,

nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí

àwọn orílẹ̀-èdè náà,

yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,

yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”

ni Olúwa wí.

32Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn;

ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”

33Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.

34Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn,

ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran.

Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé,

ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.

35Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ

kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.

36Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn,

àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran;

nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.

37Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro,

nítorí ìbínú ńlá Olúwa.

38Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀,

ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára,

àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.

26

Wọ́n fi ikú halẹ̀ mọ́ Jeremiah

1Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Dúró ní àgbàlá ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa, sọ fún gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. 3Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n. 4Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, 5àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), 6nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”

7Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa. 8Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú! 9Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.

10Nígbà tí àwọn aláṣẹ Juda gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin ọba sí ilé Olúwa, wọ́n sì mú ààyè wọn, wọ́n jókòó ní ẹnu-ọ̀nà tuntun ilé Olúwa. 11Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”

12Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́. 13Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín. 14Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi. 15Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”

16Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.”

17Lára àwọn àgbàgbà ilẹ̀ náà sì sún síwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, 18“Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko

Jerusalẹmu yóò di òkìtì

àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí

ibi gíga igbó.’

19Ǹjẹ́ Hesekiah ọba Juda tàbí ẹnikẹ́ni ní Juda pa á bí? Ǹjẹ́ Hesekiah kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ Olúwa kò ha a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”

20(Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe. 21Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti. 22Ọba Jehoiakimu rán Elnatani ọmọ Akbori lọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn. 23Wọ́n sì mú Uriah láti Ejibiti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Jehoiakimu; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)

24Ahikamu ọmọ Ṣafani ń bẹ pẹ̀lú Jeremiah, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.

27

Juda yóò sin Nebukadnessari

1Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé. 2Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ. 3Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda. 4Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ. 5Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi. 6Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀. 7Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

8“ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀. 9Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’ 10Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé. 11Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

12Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè. 13Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli? 14Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín. 15‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”

16Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn. 17Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro? 18Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 19Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà. 20Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu. 21Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti ní Jerusalẹmu: 22‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Babeli, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, Èmi yóò mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”

28

Hananiah wòlíì èké

1Ní oṣù karùn-ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọba Juda, wòlíì Hananiah ọmọ Assuri, tí ó wá láti Gibeoni, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà ọba Babeli rọrùn. 3Láàrín ọdún méjì, Èmi yóò mú gbogbo ohun èlò tí ọba Nebukadnessari; ọba Babeli kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Babeli padà wá. 4Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ”

5Wòlíì Jeremiah wí fún wòlíì Hananiah ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa. 6Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí. 7Nísinsin yìí, ìwọ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí mo sọ sí etí rẹ àti sí etí gbogbo ènìyàn. 8Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. 9Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olóòtítọ́ tí Olúwa rán, tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”

10Wòlíì Hananiah gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremiah kúrò, ó sì fọ́ ọ. 11Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé: 13“Lọ sọ fún Hananiah, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà onírin. 14Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin Nebukadnessari ọba Babeli, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

15Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́. 16Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”

17Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananiah wòlíì kú.

29

Lẹ́tà si àwọn ìgbèkùn

1Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 2Lẹ́yìn ìgbà tí Jekoniah, ọba, àti ayaba, àti àwọn ìwẹ̀fà, àti àwọn ìjòyè Juda àti Jerusalẹmu, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu. 3Ó fi lẹ́tà náà rán Eleasa ọmọ Ṣafani àti Gemariah ọmọ Hilkiah, ẹni tí Sedekiah ọba Juda rán sí Nebukadnessari ọba Babeli. Wí pé.

4Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu ní Babeli: 5“Ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín. 6Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ sí i ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá. 7Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.” 8Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárín yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá. 9Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi, Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni Olúwa wí.

10Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu. 11Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. 12Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. 13Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí. 14Èmi yóò di rí rí fún yín ni Olúwa wí, Èmi yóò sì mú yín padà kúrò ní ìgbèkùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ibi gbogbo tí Èmi ti lé yín jáde, ni Olúwa wí. Èmi yóò sì kó yín padà sí ibi tí mo ti mú kí a kó yín ní ìgbèkùn lọ.”

15Ẹ̀yin lè wí pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Babeli.” 16Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi àti ní ti gbogbo ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú yìí; àní ní ti àwọn ènìyàn yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn, 17bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ. 18Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí. 19Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 21Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an. 22Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’ 23Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Israẹli, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí Èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.

Iṣẹ́ pàtàkì tí a rán sí Ṣemaiah

24Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé, 25“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu sí Sefaniah ọmọ Maaseiah tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefaniah wí pé, 26Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin. 27Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín? 28Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Babeli wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì. 30Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé, 31“Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn ìgbèkùn wí pé: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí ní ti Ṣemaiah, ará Nehalami: Nítorí pé Ṣemaiah ti sọtẹ́lẹ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké. 32Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Wò ó, èmi yóò bẹ Ṣemaiah, ará Nehalami wò, àti irú-ọmọ rẹ̀; òun kì yóò ní ọkùnrin kan láti máa gbé àárín ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí rere náà tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi ni Olúwa wí, nítorí ó ti ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi.’ ”

30

Ìmúpadà sípò Israẹli

1Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé: 2“Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. 3Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

4Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́

láìṣe igbe àlàáfíà.

6Béèrè kí o sì rí.

Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?

Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin

tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,

tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?

7Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!

Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,

Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu

ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.

8“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,

‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,

Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.

Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.

9Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn

àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,

ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.

10“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,

má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’

ni Olúwa wí.

‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,

àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.

Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,

kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.

11Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’

ni Olúwa wí.

‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,

nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,

síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.

Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;

Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’

12“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,

bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.

13Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,

kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,

a kò sì mú yín láradá.

14Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ,

wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú.

Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ,

mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà,

nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀,

ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.

15Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,

ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?

Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga

ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.

16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,

àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;

gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

17Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,

èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí,

‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri,

Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

18“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,

èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;

ìlú náà yóò sì di títúnṣe

tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.

19Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti

ìyìn yóò sì ti máa jáde.

Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,

wọn kì yóò sì dínkù ní iye,

Èmi yóò fi ọlá fún wọn,

wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.

20Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì

níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.

Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,

ni èmi yóò fì ìyà jẹ.

21Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,

ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn.

Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,

nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’

ni Olúwa wí.

22‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,

èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”

23Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde,

ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.

24Ìbínú ńlá Olúwa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn

àwọn ìkà títí yóò fi mú

èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.

Ní àìpẹ́ ọjọ́,

òye rẹ̀ yóò yé e yín.

31

1“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.

2Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà

yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,

Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”

3Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:

“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;

mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,

4Èmi yóò tún gbé e yín sókè,

àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.

Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,

ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.

5Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà

ní orí òkè Samaria;

àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa

gbádùn èso oko wọn.

6Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde

lórí òkè Efraimu wí pé,

‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,

ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”

7Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:

“Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu;

ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.

Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,

Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;

àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’

8Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;

èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.

Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,

aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,

ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.

9Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,

wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.

Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;

ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,

nítorí èmi ni baba Israẹli,

Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.

10“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè

ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn;

‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ,

yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’

11Nítorí Olúwa ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà

ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ.

12Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni;

wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.

Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró

ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.

Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,

ìkorò kò ní bá wọn mọ́.

13Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.

Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,

dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.

Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.

14Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;

àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”

ni Olúwa wí.

1531.15: Mt 2.18.Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“A gbọ́ ohùn kan ní Rama

tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.

Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀;

kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,

nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

16Báyìí ni Olúwa wí:

“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún

àti ojú rẹ nínú omijé;

nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,”

ni Olúwa wí.

“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.

17Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”

ni Olúwa wí.

“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.

18“Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,

‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́

èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.

Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,

nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.

19Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,

mo ronúpìwàdà,

lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,

èmi lu àyà mi.

Ojú tì mí, mo sì dààmú;

nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’

20Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára

tí inú mi dùn sí bí?

Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,

síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.

Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,

èmi káàánú gidigidi fún un,”

ni Olúwa wí.

21“Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,

ṣe atọ́nà àmì,

kíyèsi òpópó ọ̀nà geere

ojú ọ̀nà tí ó ń gbà.

Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,

padà sí àwọn ìlú rẹ.

22Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,

ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin;

Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,

ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”

23Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. 25Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”

26Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

27“Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. 28Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí. 29“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:

“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n

àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’

30Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.

3131.31: Lk 22.20; 1Kọ 11.25.31.31-34: Jr 32.38-40; Hb 8.8-12; 10.16-17.“Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí,

“tí Èmi yóò bá ilé Israẹli

àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.

32Kò ní dàbí májẹ̀mú

tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,

nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,

tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti

nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.

Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”

ni Olúwa wí.

33“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá

lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:

“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,

èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.

Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;

àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.

34Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀

tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’

nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí

láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”

ni Olúwa wí.

“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,

èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

35Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

ẹni tí ó mú oòrùn

tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,

tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀

ràn ní òru;

tí ó rú omi Òkun sókè

tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

36“Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”

ni Olúwa wí.

“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun

láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”

37Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè

tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,

ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli

nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”

ni Olúwa wí.

38“Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè. 39Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa. 40Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”

32

Jeremiah ra pápá kan

1Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá Sedekiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadnessari. 2Àwọn ogun ọba Babeli ìgbà náà há Jerusalẹmu mọ́. A sì sé wòlíì Jeremiah mọ́ inú túbú tí wọ́n ń ṣọ́ ní àgbàlá ilé ọba Juda.

3Nítorí Sedekiah ọba Juda ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún ọba Babeli, tí yóò sì gbà á. 4Sedekiah ọba Juda kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kaldea, ṣùgbọ́n à ó mú fún ọba Babeli, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀. 5Yóò mú Sedekiah lọ sí Babeli tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kaldea jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ”

6Jeremiah wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 7Hanameli ọmọkùnrin Ṣallumu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó súnmọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

8“Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’

“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí. 9Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Anatoti láti ọwọ́ Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tàdínlógún fún un. 10Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òsùwọ̀n. 11Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀. 12Èmi sì fi èyí fún Baruku, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, ní ojú Hanameli, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú.

13“Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Baruku pé, 14èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀. 15Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.

16“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:

17“Háà! Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. 18O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ. 19Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀. 20O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Ejibiti. O sì ń ṣe é títí di òní ní Israẹli àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ. 21O kó àwọn Israẹli ènìyàn rẹ jáde láti Ejibiti pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá. 22Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. 23Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

24“Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe kórajọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kaldea tí ń gbóguntì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i. 25Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará Babeli, ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

26Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá pé: 27“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí? 28Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí, Èmi ṣetán láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kaldea àti fún Nebukadnessari ọba Babeli ẹni tí yóò kó o. 29Àwọn ará Kaldea tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Baali tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn.

30“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí. 31Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi. 32Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu. 33Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbi ara sí ìwà ìbàjẹ́. 34Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ṣọ́ di àìmọ́. 35Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Baali ní àfonífojì Hinnomu láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rú ẹbọ sí Moleki. Èmi kò pàṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Juda dẹ́ṣẹ̀.

36“Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba Babeli,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ nìyìí, 37Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. 3832.38-40: Jr 31.31-34.Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 39Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. 40Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn, Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi. 41Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.

42“Nítorí báyìí ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa tiwọn wá sórí wọn. 43Lẹ́ẹ̀kan sí i, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Babeli.’ 44Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Benjamini àti ní ìlú kéékèèké tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda àti ní ìlú àwọn ìlú orí òkè, àti ni àwọn ẹsẹ̀ òkè, àti ní gúúsù, èmi ó mú ìgbèkùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”

33

Ìlérí ìmúpadàbọ̀sípò

1Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀: 3‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’ 4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà 5nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn.

6“ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. 7Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. 8Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. 9Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’

10“Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí. 11Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé:

“ ‘ “Yin Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

nítorí Olúwa dára,

ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.”

Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni Olúwa wí.

12“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. 13Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

14“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ.

1533.15: Jr 23.5; Isa 4.2; Sk 3.8; 6.12.‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,

Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.

Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.

Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu.

Orúkọ yìí ni a ó máa pè é

Olúwa wa olódodo.’

1733.17: 2Sa 7.12-16; 1Ki 2.4; 1Ki 17.11-14.Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli. 18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

19Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé: 20“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́. 21Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ”

23Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 24“Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsi pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. 25Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀. 26Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọ lẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

34

Ìkìlọ̀ fún Sedekiah

134.1: 2Ki 36.17-21.Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ọmọ-ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekiah ọba Juda kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa ìlú yìí lé ọba Babeli lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀. 3Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli.

4“ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú; 5ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”

6Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu. 7Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda.

Òmìnira fún àwọn ẹrú

8Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú. 9Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Heberu lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Juda arákùnrin rẹ̀ sìn. 10Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbèkùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́. 11Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

12Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13“Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Ejibiti; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé, 14‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Heberu tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí mi. 15Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi. 16Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú.

17“Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sí mi nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrín ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrín ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-ààrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé. 18Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrín ìpín méjì náà. 19Àwọn ìjòyè Juda àti àwọn ti Jerusalẹmu, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrín àwọn ìpín méjèèjì ẹgbọrọ màlúù náà. 20Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko igbó.

21“Sedekiah ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Juda ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Babeli tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín. 22Wò ó èmi ó pàṣẹ ni Olúwa wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì bá a jà, wọn ó sì kó o, wọn ó fi iná jó o. Èmi ó sì sọ ìlú Juda dí ahoro.”

35

Àwọn Rekabu

1Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: 2“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

3Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu. 4Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. 5Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

6Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé. 7Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’ 8Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa. 9Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

12Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13“Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 14‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 15Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 16Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17“Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’ 19Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

36

Jehoiakimu jó ìwé kíká Jeremiah

1Ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé: 2“Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Israẹli àti ti Juda, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Josiah títí di òní. 3Ó lè jẹ́ wí pé ilé Juda yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”

4Nígbà náà ni Jeremiah pe Baruku ọmọ Neriah, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá a sọ fún, Baruku sì kọ láti ẹnu Jeremiah, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún un sórí ìwé kíká náà. 5Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa. 6Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn. 7Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”

8Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa. 9Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda. 10Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

11Nígbà tí Mikaiah ọmọ Gemariah ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà; 12Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Eliṣama akọ̀wé, Delaiah ọmọ Ṣemaiah, Elnatani ọmọ Akbori, Gemariah ọmọ Ṣafani àti Sedekiah ọmọ Hananiah àti gbogbo àwọn ìjòyè. 13Lẹ́yìn tí Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Baruku kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn. 14Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jehudu ọmọ Netaniah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Kuṣi sí Baruku wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Baruku ọmọ Neriah wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀. 15Wọ́n sì wí fún pé, “Jókòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”

Nígbà náà ni Baruku sì kà á ní etí wọn. 16Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Baruku pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.” 17Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”

18Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”

19Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”

20Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. 21Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba. 22Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀. 23Nígbà tí Jehudu ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé kíká náà fi jóná tán. 24Síbẹ̀, ọba àti gbogbo àwọn ẹ̀mẹwà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá. 25Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn. 26Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

27Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28“Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.” 30Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé, Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru. 31Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”

32Nígbà náà ni Jeremiah mú ìwé kíká mìíràn fún Baruku akọ̀wé ọmọ Neriah, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jehoiakimu ọba Juda ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.

37

Jeremiah nínú túbú

1Sedekiah ọmọ Josiah sì jẹ ọba ní ipò Jehoiakini ọmọ Jehoiakimu ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Juda. 2Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremiah.

3Sedekiah ọba sì rán Jehukali ọmọ Ṣelemiah àti Sefaniah ọmọ Maaseiah sí Jeremiah wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

4Nígbà yìí Jeremiah sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrín àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú. 5Àwọn ọmọ-ogun Farao ti jáde kúrò nílẹ̀ Ejibiti àti nígbà tí àwọn ará Babeli tó ń ṣàtìpó ní Jerusalẹmu gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.

6Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì Ọlọ́run wá: 7“Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ fún ọba àwọn Juda tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Ejibiti. 8Nígbà náà ni àwọn ará Babeli yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’

9“Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Babeli yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú.’ Wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. 10Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ-ogun Babeli tí ń gbóguntì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”

11Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ-ogun Babeli ti kúrò ní Jerusalẹmu nítorí àwọn ọmọ-ogun Farao. 12Jeremiah múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Benjamini láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrín àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀. 13Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.”

14Jeremiah sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Babeli.” Ṣùgbọ́n Irijah ko gbọ́ tirẹ̀, dípò èyí a mú Jeremiah, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè. 15Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.

16Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́. 17Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?”

Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.”

18Nígbà náà, Jeremiah sọ fún ọba Sedekiah pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú? 19Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín wí pé ọba Babeli kò ní gbóguntì yín wá? 20Ṣùgbọ́n ní báyìí, olúwa mi ọba, èmí bẹ̀ ọ. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jonatani akọ̀wé, àfi kí n kú síbẹ̀.”

21Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.

38

Wọ́n sọ Jeremiah sínú kànga gbígbẹ

1Ṣefatia ọmọ Mattani, Gedaliah ọmọ Paṣuri, Jehukali ọmọ Ṣelemiah, àti Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ ohun tí Jeremiah ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé, 2“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Babeli yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’ 3Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun ọba Babeli; tí yóò sì kó wa nígbèkùn.’ ”

4Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ-ogun tókù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ìre fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”

5Sedekiah ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhun láti takò yín.”

6Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà.

7Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini. 8Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé, 9“Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”

10Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”

11Ebedimeleki kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremiah lọ nínú kànga. 12Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.” 13Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú.

Sedekiah bi Jeremiah lẹ́ẹ̀kan sí i

14Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ pe, Jeremiah òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnu ibodè kẹta nílé Olúwa. Ọba sì sọ fún Jeremiah pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”

15Jeremiah sì sọ fún Sedekiah pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò nípa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”

16Ṣùgbọ́n ọba Sedekiah búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremiah wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò nípa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”

17Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún Sedekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè ọba Babeli, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó ní iná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láààyè. 18Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babeli, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Babeli. Wọn yóò sì fi iná sun ún, ìwọ gan an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’ ”

19Ọba Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Babeli, nítorí pé àwọn ará Babeli lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.”

20Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà. 21Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fihàn mí. 22Gbogbo àwọn obìnrin tókù ní ààfin ọba Juda ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè ọba Babeli. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé:

“ ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ,

wọ́n sì borí rẹ.

Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀;

àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’

23“Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Babeli. Ìwọ gan an kò ní bọ́ níbẹ̀, ọba Babeli yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.”

24Nígbà náà ni Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú. 25Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’ 26nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jonatani láti lọ kú síbẹ̀.’ ”

27Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremiah láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti ọba jọ sọ.

28Jeremiah wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jerusalẹmu:

39

Ìṣubú Jerusalẹmu

1Ó sì ṣe, nígbà tí a kó Jerusalẹmu, ní ọdún kẹsànán Sedekiah, ọba Juda, nínú oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun ti Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, wọ́n sì dó tì í. 2Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Sedekiah, ni a wó odi ìlú náà. 3Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli wá, wọ́n sì jókòó ní àárín ẹnu ibodè, àní Nergali-Ṣareseri ti Samgari, Nebo-Sarsikimu olórí ìwẹ̀fà, Nergali-Ṣareseri, olórí amòye, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli yóò kú. 4Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.

5Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 6Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda. 7Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.

8Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu. 9Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú. 10Ṣùgbọ́n Nebusaradani olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Juda, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.

11Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé: 12“Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.” 13Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli, 14ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15Nígbà tí Jeremiah wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé: 16“Lọ sọ fún Ebedimeleki ará Kuṣi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi ṣetán láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ. 17Ṣùgbọ́n, Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí. A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù. 18Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, ni Olúwa wí.’ ”

40

A tú Jeremiah sílẹ̀

1Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli. 2Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi. 3Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.” 5Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremiah pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú Juda, kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.”

Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ. 6Báyìí ni Jeremiah lọ sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ní Mispa, ó sì dúró tì í láàrín àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà.

Wọ́n ṣe ikú pa Gedaliah

7Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀-èdè náà gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀ ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ tálákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀, 8wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ní Mispa; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, Johanani àti Jonatani ọmọkùnrin ti Karea, Seraiah ọmọkùnrin Tanhumeti tí í ṣe ọmọkùnrin Efai ará Netofa àti Jesaniah ọmọkùnrin Maakati àti àwọn ènìyàn wọn. 9Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu, ọmọkùnrin ti Ṣafani ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn Babeli.” Ó sọ wí pé, “Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín. 10Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mispa láti ṣojú yín níwájú Babeli tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́wọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ìlú tí ẹ ti gbà.”

11Nígbà tí gbogbo àwọn Juda ní Moabu, Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba Babeli ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní Juda, àti pé ó ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn. 12Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Juda sọ́dọ̀ Gedaliah ní Mispa láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi.

13Johanani ọmọkùnrin ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ Gedaliah wá ní Mispa. 14Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Baalisi ọba àwọn Ammoni ti rán Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọkùnrin ti Ahikamu kò gbà wọ́n gbọ́.

15Nígbà náà ni Johanani ọmọkùnrin Karea sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Gedaliah ní Mispa pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Juda sì parun?”

16Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọ Ahikamu sọ fún Johanani ọmọ Karea pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Iṣmaeli kì í ṣe òtítọ́.”

41

1Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.

4Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀, 5àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa. 6Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah jáde kúrò láti Mispa láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sọkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu.” 7Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan. 8Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Iṣmaeli pé, “Má ṣe pa wá! Àwa ní ọkà àti barle, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yòókù. 9Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.

10Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni.

11Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe. 12Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni. 13Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀. 14Gbogbo àwọn ènìyàn tí Iṣmaeli ti kó ní ìgbèkùn ní Mispa yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Johanani ọmọ Karea. 15Ṣùgbọ́n Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Johanani, wọ́n sì sálọ sí Ammoni.

Sísá lọ sí Ejibiti

16Lẹ́yìn náà Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mispa; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu. Àwọn ọmọ-ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gibeoni. 17Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n dúró ní Geruti Kimhamu ní ẹ̀bá Bẹtilẹhẹmu ní ọ́nà ìrìnàjò wọn sí Ejibiti. 18Láti gba àwọn Babeli sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu èyí tí ọba Babeli ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómìnà lórí ilẹ̀ náà.”

42

1Nígbà náà ní gbogbo àwọn olórí ogun àti Johanani ọmọkùnrin Karea àti Jesaniah ọmọkùnrin Hoṣaiah àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá. 2Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù. 3Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.”

4Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”

5Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremiah wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrín wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa. 6Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, èyí tí àwa ń rán ọ sí, kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

7Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá, 8O sì pe Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni ńlá. 9Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ síwájú mi. 10Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín. 11Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀. 12Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’

13“Ṣùgbọ́n sá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín. 14Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Ejibiti; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’ 15nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀. 16Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyanu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Ejibiti àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí. 17Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’ 18Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’

19“Ẹ̀yin yòókù Juda, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Ejibiti.’ Ẹ mọ èyí dájú, èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí, 20pé àṣìṣe ńlá gbá à ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’ 21Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín. 22Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ mọ èyí dájú pé, ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó.”

43

1Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan. 2Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’ 3Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.”

4Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda. 5Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká. 6Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusaradani balógun ẹ̀ṣọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, àti Jeremiah wòlíì náà àti Baruku ọmọ Neriah. 7Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.

8Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá: 9“Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi. 10Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí. Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli, Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ. 11Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà. 12Yóò dá, iná sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Ejibiti òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà. 13Ní tẹmpili ni yóò ti fọ́ ère ilé oòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti túútúú, yóò sì sun àwọn tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti.’ ”

44

Àjálù nítorí ṣinṣin òrìṣà

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró. 6Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.

7“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.

11“Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run. 12Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn. 13Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu. 14Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.”

15Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16“Wọn sì wí pé, àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa. 17Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi. 18Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”

19Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”

20Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, 21“Ṣe Olúwa kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú. 22Nígbà tí Olúwa kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí. 23Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”

24Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’

“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí, ‘pé kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra, “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán. 28Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín.

29“ ‘Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’ 30Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”

45

Ìlérí Ọlọ́run fún Baruku

1Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ fún ọ, Baruku. 3Ìwọ wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora mi, àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.’ ” 4Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èyí tí èmi ti kọ́ ni èmi yóò wò lulẹ̀, àti èyí tí èmi ti gbìn ni èmi yóò fàtu, àní ní orí gbogbo ilẹ̀. 5Ṣé ìwọ sì ń wá ohun títóbi fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ìwọ bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ.’ ”

46

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa Ejibiti

146.1-28: Isa 19; El 29.1–32.32; Sk 14.18-19.Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè.

2Nípa Ejibiti.

Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

3“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,

kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!

4Ẹ di ẹṣin ní gàárì,

kí ẹ sì gùn ún.

Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ

pẹ̀lú àṣíborí yín!

Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,

kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

546.5: Jr 6.25; 20.3,10; 49.29; Sm 31.13.Kí ni nǹkan tí mo tún rí?

Wọ́n bẹ̀rù,

wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,

wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.

Wọ́n sá,

wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,

ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”

ni Olúwa wí.

6“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,

tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.

Ní àríwá ní ibi odò Eufurate

wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

7“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,

tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?

8Ejibiti dìde bí odò náà,

bí omi odò tí ń ru.

Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’

Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.

9Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,

ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.

Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,

àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;

àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.

10Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,

títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.

Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ

ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.

11“Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,

ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.

Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,

kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.

12Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,

igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.

Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,

àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”

13Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:

14“Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,

sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:

‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,

nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

15Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?

Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.

16Wọn yóò máa ṣubú léraléra

wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.

Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà

sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,

kúrò níbi idà àwọn aninilára.’

17Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,

‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,

ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

18“Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,

ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,

“Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti

gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.

19Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti

pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ

nítorí Memfisi yóò di ahoro

a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.

20“Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti

ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,

ó dé láti àríwá.

21Àwọn jagunjagun rẹ̀

dàbí àbọ́pa akọ màlúù.

Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,

wọn ó sì jùmọ̀ sá,

wọn kò ní le dúró,

nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn

àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.

22Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá

bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.

Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,

gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.

23Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni Olúwa wí,

“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀.

Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.

24A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti,

a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

25Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

27“Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,

má fòyà, ìwọ Israẹli.

Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,

àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.

Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,

kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.

28Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,

nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,

láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.

Èmi kò ní run yín tán.

Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,

èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

47

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ará Filistini

147.1-7: Isa 14.29-31; El 25.15-17; Am 1.6-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.

2Báyìí ni Olúwa wí:

“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,

wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.

Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,

ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.

Àwọn ènìyàn yóò kígbe,

gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu

3nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára

nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá

àti iye kẹ̀kẹ́ wọn.

Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;

ọwọ́ wọn yóò kákò.

4Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé

láti pa àwọn Filistini run,

kí a sì mú àwọn tí ó là

tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.

Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,

àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.

5Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.

A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;

ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,

ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6“Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,

yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?

Padà sínú àkọ̀ rẹ;

sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’

7Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,

nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,

nígbà tí ó ti pa á láṣẹ

láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”

48

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa Moabu

148.1-47: Isa 15.1–16.14; 25.10-12; El 25.8-11; Am 2.1-3; Sf 2.8-11.Nípa Moabu.

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí:

“Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun.

A dójútì Kiriataimu, a sì mú un,

ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.

2Moabu kò ní ní ìyìn mọ́,

ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,

‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’

Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,

a ó fi idà lé e yín.

3Gbọ́ igbe ní Horonaimu,

igbe ìrora àti ìparun ńlá.

4Moabu yóò di wíwó palẹ̀;

àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

5Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,

wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;

ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu

igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;

kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.

7Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,

a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,

Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn

pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.

8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,

ìlú kan kò sì ní le là.

Àfonífojì yóò di ahoro

àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,

nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

9Fi iyọ̀ sí Moabu,

nítorí yóò ṣègbé,

àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro

láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

10“Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa,

ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

11“Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá

bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,

tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì

kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.

Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,

òórùn rẹ̀ kò yí padà.

12Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,

“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò

tí wọ́n ó sì dà á síta;

wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,

wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.

13Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi,

bí ojú ti í ti ilé Israẹli

nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.

14“Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá,

alágbára ní ogun jíjà’?

15A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;

a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”

ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16“Ìṣubú Moabu súnmọ́;

ìpọ́njú yóò dé kánkán.

17Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.

Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ

títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’

18“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,

kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,

ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni,

nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run

yóò dojúkọ ọ́

yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.

19Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,

ìwọ tí ń gbé ní Aroeri.

Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà

‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’

20Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀.

Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe!

Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé,

a pa Moabu run.

21Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ,

sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,

22sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu,

23sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,

24sórí Kerioti àti Bosra,

sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.

25A gé ìwo Moabu kúrò,

apá rẹ̀ dá,”

ni Olúwa wí.

26“Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí

nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,

jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀,

kí ó di ẹni ẹ̀gàn.

27Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ?

Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè

tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́

nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

28Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta,

ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu.

Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀

sí ẹnu ihò.

29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:

àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀

àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.

30Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí,

“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.

31Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabu

fún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara,

mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.

32Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún

ìwọ àjàrà Sibma.

Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun,

wọn dé Òkun Jaseri.

Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ,

ìkórè èso àjàrà rẹ.

33Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò

nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu.

Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí;

kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà,

wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.

34“Ohùn igbe wọn gòkè

láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi,

láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi,

nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ.

35Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí

ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga

àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”

ni Olúwa wí.

36“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè,

ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.

Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.

37Gbogbo orí ni yóò pá,

gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò,

gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́,

àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.

38Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu,

àti ní ìta rẹ̀,

nítorí èmi ti fọ́ Moabu

bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,”

ni Olúwa wí.

39“Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,

tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!

Báwo ni Moabu ṣe yí

ẹ̀yìn padà ní ìtìjú!

Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti

ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”

40Báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀

ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu.

41Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà.

Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu

yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.

42A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí

orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.

43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè

ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,”

Olúwa wí.

44“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún

ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn

ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta

nínú ọ̀fìn ní à ó mú

nínú okùn dídè nítorí tí

èmi yóò mú wá sórí

Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,”

Olúwa wí.

45“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni

àwọn tí ó sá dúró láìní agbára,

nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni,

àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni,

yóò sì jó iwájú orí Moabu run,

àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.

46Ègbé ní fún ọ Moabu!

Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbé

a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì

àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn.

47“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ

Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,”

ni Olúwa wí.

Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.

49

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa Ammoni

149.1-6: El 21.28-32; 25.1-7; Am 1.13-15; Sf 2.8-11.Nípa Ammoni.

Báyìí ni Olúwa wí,

“Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin?

Israẹli kò ha ní àrólé bí?

Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi?

Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

2Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,”

ni Olúwa wí;

“nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun

ní Rabba tí Ammoni;

yóò sì di òkìtì ahoro,

gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná.

Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn,

àwọn tí ó ti lé e jáde,”

ni Olúwa wí.

3“Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún!

Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba!

Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀.

Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà,

nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn,

pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

4Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ,

ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso?

Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́,

ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,

‘Ta ni yóò kò mí lójú?’

5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ

láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”

ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

6Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan

tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,”

ni Olúwa wí.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu

749.7-22: Isa 34; 63.1-6; El 25.12-14; 35; Am 1.11-12; Ml 1.2-5.Nípa Edomu.

Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani?

Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?

Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò,

ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,

nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,

ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.

9Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;

ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?

Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní

kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?

10Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,

èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,

nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.

Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti

àwọn ará ilé rẹ yóò parun.

Wọn kò sì ní sí mọ́.

11Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀

èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.

Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”

12Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. 13Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

14Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa,

a rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé,

ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.

15“Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di

kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo;

ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.

16Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú

ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;

ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta,

tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga

síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;

láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”

ni Olúwa wí.

17“Edomu yóò di ahoro

gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì

fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.

18Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu

àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú

tí ó wà ní àyíká rẹ,”

Olúwa wí.

“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;

kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

19“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,

Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.

Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?

Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?

Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

20Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí

Olúwa ní fún Edomu,

ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani.

Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde;

pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.

21Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn,

a ó gbọ́ igbe wọn

ní Òkun pupa.

22Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,

yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra.

Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun

Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Damasku

23Nípa Damasku.

“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,

wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.

24Damasku di aláìlera,

ó pẹ̀yìndà láti sálọ,

ìwárìrì sì dé bá a;

ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú,

ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;

ìlú tí mo dunnú sí.

26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó,

gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”

Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

27“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,

yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”

Ọ̀rọ̀ nípa Kedari àti Hasori

28Nípa ìlú Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ,

èyí ni ohun tí Olúwa sọ,

“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ ìlú Kedari,

kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.

2949.29: Jr 6.25; 20.3,10; 46.5; Sm 31.13.Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ;

àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà

pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn.

Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé,

‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’

30“Sálọ kíákíá!

Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,”

ni Olúwa wí.

“Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́.

31“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn,

èyí tí ó gbé ní àìléwu,”

Olúwa wí.

“Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin,

àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé.

32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù

àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun.

Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.

Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”

báyìí ní Olúwa wí.

33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá,

ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,

kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa Elamu

34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:

“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu,

ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

36Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin

àgbáyé lòdì sí Elamu.

Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé,

kò sí orílẹ̀-èdè

tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.

37Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn,

àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn,

Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,

àní, ìbínú gbígbóná mi,”

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

“Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.

38Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu,

èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,”

báyìí ni Olúwa wí.

39“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ

Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,”

báyìí ni Olúwa wí.

50

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Babeli

150.1–51.64: Isa 13.1–14.23; 47.1-15; Hk 1–2.Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:

2“Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,

kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀

ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé,

‘A kó Babeli,

ojú tí Beli,

a fọ́ Merodaki túútúú,

ojú ti àwọn ère rẹ̀,

a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’

3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò

sì máa gbóguntì wọ́n.

Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò

sá kúrò ní ìlú yìí.

4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”

ni Olúwa wí,

“Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá,

àwọn, àti àwọn ọmọ Juda,

wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí

Olúwa Ọlọ́run wọn.

5Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni,

ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀,

wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa

ní májẹ̀mú ayérayé,

tí a kì yóò gbàgbé.

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,

àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà,

wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè

wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,

wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ

àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi

nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé

òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

8“Jáde kúrò ní Babeli,

ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀,

kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran.

9Nítorí pé èmi yóò ru,

bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè

ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;

láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò

dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo.

10A ó dààmú Babeli,

gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,”

ni Olúwa wí.

11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,

ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn

fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù,

ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.

12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ

yóò sì gba ìtìjú.

Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.

13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;

ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.

Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò

fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli

àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà.

Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.

15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà!

Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,

níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,

gbẹ̀san lára rẹ̀.

Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli,

àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè!

Nítorí idà àwọn aninilára

jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,

kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,

kìnnìún sì ti lé e lọ.

Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,

àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli

fa egungun rẹ̀ ya.”

18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí,

“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀

gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.

19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli

padà wá pápá oko tútù rẹ̀

òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,

a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè

Efraimu àti ní Gileadi.

20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”

ni Olúwa wí,

“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,

ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;

àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan

nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn

tí ó ń gbé ní Pekodi.

Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,”

ni Olúwa wí,

“Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.

22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà

ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.

23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó,

lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé!

Báwo ní Babeli ti di ahoro

ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.

24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀

fún ọ ìwọ Babeli,

kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,

o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.

25Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde,

nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun

ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.

26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo,

sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀,

ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà,

kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun,

ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.

27Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ,

jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!

Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,

àkókò ìbẹ̀wò wọn.

28Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá,

sì sọ ní Sioni,

Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,

ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli,

ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.

Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀

gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe,

ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga

Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.

30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀

yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn

ológun lẹ́nu mọ́,”

Olúwa wí.

31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,”

ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

“nítorí ọjọ́ rẹ ti dé,

àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.

32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú,

kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde.

Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,

èyí tí yóò sì jo run.”

33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:

“A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli

lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú.

Gbogbo àwọn tí ó kó wọn

nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin

wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.

34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára,

Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀.

Yóò sì gbe ìjà wọn jà,

kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà;

ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

35“Idà lórí àwọn Babeli!”

ni Olúwa wí,

“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli,

àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.

36Idà lórí àwọn wòlíì èké

wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,

wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.

37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀

àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.

Wọn yóò di obìnrin.

Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!

38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.

Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,

àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù

pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,

abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,

a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,

bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra

pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,”

ni Olúwa wí,

“torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀;

ènìyàn ki yóò gbé nínú rè.

41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá;

orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń

gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.

42Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,

wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.

Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ.

Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.

43Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,

ọwọ́ wọn sì rọ,

ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.

44Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani

sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,

Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.

Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?

Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?

Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

45Nítorí náà, gbọ́ ohun tí

Olúwa sọ nípa Babeli,

ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Babeli:

n ó sì pa agbo ẹran wọn run.

46Ní ohùn igbe ńlá pé;

a kò Babeli, ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì,

a sì gbọ́ igbe náà

láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

51

1Ohùn ti Olúwa wí nìyìí:

“Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè

sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai,

2Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli

láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo;

wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà

ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.

3Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀,

jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀.

Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí;

pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

4Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Babeli,

tí wọn yóò sì fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.

5Nítorí pé Juda àti Israẹli ni

Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn

kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.

651.6,9,45: Jr 50.8; 2Kọ 6.17; If 18.4.“Sá kúrò ní Babeli!

Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!

Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí;

yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.

751.7-8: Jr 25.15; If 14.8,10; 16.19; 17.4; 18.3.Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa;

ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí.

Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀,

wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.

8Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́.

Ẹ hu fun un!

Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ,

bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

9“ ‘À bá ti wo Babeli sàn,

ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,

kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,

ó ga àní títí dé òfúrufú.’

10“ ‘Olúwa ti dá wa láre,

wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa

Ọlọ́run wa ti ṣe.’

11“Ṣe ọfà rẹ ní mímú,

mú àpáta!

Olúwa ti ru ọba Media sókè,

nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run.

Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

12Gbé àsíá sókè sí odi Babeli!

Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí,

ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri,

ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́

Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,

òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.

1351.13: If 17.1.Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀,

tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé,

àní àsìkò láti ké ọ kúrò!

14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀,

Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú,

wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.

15“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,

o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,

o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.

16Nígbà tí ará omi ọ̀run hó

ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.

Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,

ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.

17“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀,

olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀.

Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn;

wọn kò ní èémí nínú.

18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà,

nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.

19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí;

nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,

àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún,

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi,

ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú,

èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.

21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;

èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú

èmi ó pa awakọ̀,

22pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,

pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbàlagbà àti ọmọdé,

pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.

23Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn,

àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú,

èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú,

èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú.

24“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,”

ni Olúwa wí.

25“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun

ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”

ni Olúwa wí.

“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,

èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,

Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

26A kò ní mú òkúta kankan láti

ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí

fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di

ahoro títí ayé,”

Olúwa wí.

27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà!

Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!

Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀,

pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́:

Ararati, Minini àti Aṣkenasi.

Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,

rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.

28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀,

àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀,

àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.

29Ilẹ̀ wárìrì síyìn-ín sọ́hùn-ún,

nítorí pé ète Olúwa, sí Babeli dúró,

láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà

tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.

30Gbogbo àwọn jagunjagun

Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn.

Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.

Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,

gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn

láti sọ fún ọba Babeli pé

gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.

32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́

ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí:

“Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run,

ó ti mú kí ìdààmú bá wa,

ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.

Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.

Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,

lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde.

35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,”

èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí.

“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,”

ni Jerusalẹmu wí.

36Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí

ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,

èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.

37Babeli yóò parun pátápátá,

yóò sì di ihò àwọn akátá,

ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

38Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù

bí ọmọ kìnnìún.

39Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,

èmi yóò ṣe àsè fún wọn,

èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó

tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín,

lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,”

ni Olúwa wí.

40“Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn

tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́.

41“Báwo ni Ṣeṣaki yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.

Irú ìpayà wo ni yóò bá

Babeli láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!

42Òkun yóò ru borí Babeli,

gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Babeli.

43Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,

ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn

kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.

44Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli

àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì.

Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́.

Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.

45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀

ẹ̀yin ènìyàn mi!

Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!

Sá fún ìbínú ńlá Olúwa.

46Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú

tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí

a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;

àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,

òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá

ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.

47Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan

nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli;

gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì

gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.

48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,

yóò sì kọrin lórí Babeli:

nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”

ni Olúwa wí.

49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli,

gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.

50Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró.

Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,

ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

51“Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:

ìtìjú ti bò wá lójú

nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

52“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,

“tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀,

àti àwọn tí ó gbọgbẹ́

yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

53Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,

bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ,

síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,”

Olúwa wí.

54“Ìró igbe láti Babeli,

àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea!

55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ,

ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;

àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀,

àní sórí Babeli;

a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:

nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,

yóò san án nítòótọ́.

57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,

àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀

àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,

wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”

ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá,

ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:

tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,

àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,

tí àárẹ̀ sì mú wọn.”

59Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó. 60Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli. 61Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 62Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’ 6351.63-64: If 18.21.Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárín odò Eufurate. 64Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Babeli yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ”

Títí dé ìhín ni ọ̀rọ̀ Jeremiah.

52

Ìṣubú Jerusalẹmu

1Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá. 252.2: 2Ọb 24.18–25.30; 2Ki 36.11-13.Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 3Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀.

Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.

4Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀. 5Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá ọba Sedekiah.

6Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 7Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ. 8Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká. 9Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn.

Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 10Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

12Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàndínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńlá ńlá. 14Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 15Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 16Ṣùgbọ́n Nebusaradani, balógun ìṣọ́ fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti ro oko.

17Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli. 18Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ. 19Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

20Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú. 22Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra. 23Pomegiranate mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.

24Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 25Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà. 26Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 27Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati.

Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

28Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.

Ní ọdún keje ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda.

29Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadnessari

o kó ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) láti Jerusalẹmu.

30Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù

tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín márùn-ún (745).

Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún (4,600).

Ìtúsílẹ̀ Jehoiakimu

31Ní ọdún kẹtàdínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá. 32Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 33Nítorí náà, Jehoiakini pàrọ̀ aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34Ní ojoojúmọ́ ni ọba Babeli ń fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè, títí di ọjọ́ kú rẹ̀.